Tollgate Fee: Àwọn ọmọ Naijiria ní àsìkò sísan owó 'tollgate' kò tíì tó báyìí

Oríṣun àwòrán, @johnnysleek
Awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni fi erongba wọn lede lori ẹrọ ayelujara bayi, lẹyin ti ijọba apapọ kede ipadabọ owo oju popo.
Bi awọn kan ṣe lero pe oyẹ ki awọn ọmọ Naijiria ma san owo 'Toll gate' yii, awọn miran ni asiko ko ti to fun owo oju opopona.
Nwa Anam sọ loju opo Twitter rẹ pe owo oju opopna yii yoo mu nnkan le sii fun awọn ọmọ orilẹ-ede yii ni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
O ni o yẹ ki ijọba kọkọ tun awọn ọna to ti baje ṣe ki wọn to bere owo oju opopona.
Triumph lori Twitter da si ọrọ naa nigba to ni "Anfani wo ni owo oju opopona yoo ṣe awọn ọmọ Naijiria nigba ti ọpọlọpọ ọna ijọba apapọ ti dẹnu kọlẹ?
Abami Ẹda ni tirẹ ni iwa jibiti ni ijọba fẹ wu ni bi wọn ṣe fẹ bẹrẹ si ni gba owo oju opopona.
Deboye Oyewole loju opo Facebook ni, o dara ki ijọba apapọ bẹrẹ si gba owo oju opopona, nitori yoo jẹ afikun owo abẹle fun ijọba yatọ si owo epo bentiro.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3

End of X post, 4

End of X post, 5

End of X post, 6
Tollgate Fee: Ìjọba ní Naijiria yóò padà sí ní san owó 'tollgate

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ijọba ti ni awọn ọmọ Naijiria yoo pada bẹrẹ si ni san owo oju popo ni gbogbo opopona ijọba apapọ.
Eyi waye lẹyin ọdun mẹẹdogun ti ijọba aarẹ tẹlẹri, Olusegun Obasanjo tu gbogbo awọn ibudo naa fọnka.
Amọ, Minisita fun ọrọ isẹ ati ile gbigbe, Babatunde Fashola sọ eyi lẹyin ipade awọn minisita se pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari nilu Abuja.
Fashola ni ijọba gbe igbesẹ naa lati pa owo wọle fun ijọba lati tun awọn opopona to ti bajẹ se kaakiri orilẹede Naijiria.
Bakan naa lo ṣakawe awọn orilẹ-ede gbogbo ti wọn ti n san owo oju ẹnu ibode laarin ilu yii.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
O tun mẹnuba idagbasoke ti sisan owo yii yoo mu wa fun gbogbo olugbe Naijiria.