Jazz music: Ayọ̀ tó ń bẹ nínú orin Jazz

Olakunle Tejuoso ninu ile itaja rẹkọọdu the Jazzhole Lagos

Oríṣun àwòrán, AP

Àkọlé àwòrán, Olakunle Tejuoso at his record and book store in Lagos

Ni aarin ile itaja rẹkọọdu orin rẹ, The Jazzhole, lo duro si.

Ọlakunle Tẹjuoṣo mura ninu aṣọ Buba ati Sokoto rẹ, oun atawọn oṣiṣẹ rẹ si n sọrọ pọ bi wọn ṣe n tun iwe to wa lori awọn atẹ ifiwe si to.

Bi o si ti n ṣe eyi naa lo n ranti igba ewe rẹ.

"Lakọkọ naa, lati kekere ni mo ti maa n la ala pe emi naa yoo ni ile itaja rẹkọọdu temi...nitori lati kekere ni mo ti maa n ṣe akojọpọ awọn awo orin.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

Nnkan ti mo maa n ṣe niyi lẹyin ti mo ba kuro ni ileewe" ni ọrọ to ti ẹnu Tẹjuoṣo jade.

Ile itaja rẹkọọdu, The Jazzhole ti o wa ni opopona Awolọwọ ni ilu Eko bẹrẹ karakata ni ọdun 1991 ni ile kekere kan ni apa ibi kan nilu Eko kan naa.

Iwaju ile The Jazzhole

Oríṣun àwòrán, Princess I. Abumere/BBC

Àkọlé àwòrán, The Jazzhole

Lasiko yii to jẹ wi pe orin takasufe Afrobeats lo gbode kan lori awọn ileeṣẹ redio ati ile ijo gbogbo, The Jazzhole ṣi gbin ara rẹ kalẹ gẹgẹ bii ibudo akojọpọ oniruuru orin.

Nipasẹ eyii, ile itaja rẹkọọdu ati iwe naa ti sọ ara rẹ di ọkan pataki lara awọn ibudo ti eeyan ti lee ri orin igba atijọ gbọ seti.

"Nitori ati maa ta orin Jazz ati orin ilẹ Adulawọ ni a ṣe ṣi ile itaja rẹkọọdu yii silẹ."

Ninu ile itaja rẹkọọdu the Jazzhole

Oríṣun àwòrán, Princess I. Abumere/BBC

Àkọlé àwòrán, The Jazzhole houses jazz music from different eras

Orin Jazz ni iyi pupọ lawọn ọdun ogun si ọgbọn sẹyin ṣugbọn o ti di agbọnrin eṣi bayii.

"Awọn saraki-saraki eeyan lonibara mi nigba naa, awo orin igbalode CD ko si tii wọpọ nigba naa.

Yatọ si pe wọn n ra awo orin, wọn mọ iyi orin nitori pe wọn ti wo oniruuru olorin.

"Gbogbo wọn lo ti fẹrẹ lọ soke okun tan ti wọn si lowo lati lọ sawọn ajọdun orin ati ijo kaakiri agbaye."

Atẹ awo orin ni The Jazzhole

Oríṣun àwòrán, Princess I. Abumere

Àkọlé àwòrán, Yatọ si pe wọn n ra awo orin, wọn mọ iyi orin nitori pe wọn ti wo oniruuru olorin.

Amọṣa Tẹjuoṣo ṣalaye pe awọn eeyan tun ti n poungbẹ fun orin Jazz bayii.

"Iyatọ wa laarin awọn ọdọ iwoyii si awọn ọdọ igba tiwa."

Awo orin aye atijọ

Oríṣun àwòrán, Princess I. Abumere/BBC

Àkọlé àwòrán, "Nitori ati maa ta orin Jazz ati orin ilẹ Adulawọ ni a ṣe ṣi ile itaja rẹkọọdu yii silẹ."

Ode Alujo orin:

Ilee itaja orin The Jazzhole tun maa n gbalejo ode alujo orin.

Tẹjuoṣo ni gbogbo ode alujo orin ti wọn gbe kalẹ wa lati ta awọn orin naa.

Ọlọkan-o-jọkan awọn olorin bii Aṣa, Brymo ati Nneka ni wọn ti lọ ṣere nibẹ.

Itage ti Nneka ti kọrin ni The Jazzhole

Oríṣun àwòrán, Princess I. Abumere/BBC

Nitirẹ, iyawo Tẹjuoṣo, ti wọn jijọ ni ile orin naa ni Fatai Rolling Dollars no oun ko lee gbagbe.

O ni awọn olorin agbagba wọnyii lo n wu oun nigbakugba.

Gbogbo awọn olorin naa lo si ni ode wọn jẹ manigbagbe.