Ọmọkùnrin kan sin Baba rẹ̀ láàyè torì pé ó gbàgbọ́ pé oṣó ni!

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orọ yii so ọlọgbọn kọ, o so were kọ ni awọn agbofinro Mozambique sọ.
Baba agba, ẹni ọdun marundinlaadọrin kan ni ọlọjọ ti de fun lataari igbesẹ ọmọ rẹ sii.
Guusu orilẹ-ede Mozambique ni ọdọmọkunrin kan ti sin baba rẹ laaye ki baba naa to gbẹmi mi.
Awọn ọlọpaa ilẹ Mozambique ṣalaye pe, ọdọmọkunrin yii gbagbọ pe oṣó ni baba rẹ lo ṣe gbe e sin laaye.
Oga agba agbofinro ni Mozambique ni awọn ti mu eniyan ogun ti awọn furasi si gbaga nitori ọrọ yii.
Wọn ni ẹbi baba agba yii ni awọn eniyan ti ọwọ tẹ naa ti wọn ni wọn fura pe oṣo ni baba yii.
Iroyin ti a gbọ ni pe wọn ni eniyan mẹwaa lo ti ku ninu ẹbi wọn lati ọdun 2000 ni eyi ti wọn gbagbọ pe baba yii lo n ṣe iku pa wọn.
Awọn agbofinro Mozambique ni awọn ṣi n wa oniṣegun to sọ fun mọlẹbi yii pe ọwọ baba agba naa ko mọ́ si awọn mọlẹbi rẹ.














