Xenophobia Attack - Ilẹ South Afrika kò ní gbàgbé Nàìjíríà fún àtìlẹyìn wọn.

Aare Naijiria ati ti South Afrika

Oríṣun àwòrán, BASHIL AHMAD

Àkọlé àwòrán, Aare Buhari ati Ramaphosa ti ile South Afrika n sọrọ papọ ki alaafia le jọba
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ ilẹ South Afrika, Cyril Ramaphosa ti fi idunnu rẹ han si orilẹ-ede Naijiria lori ipa ti o ti ko fun idagbasoke South Africa sẹyin.

Aarẹ naa ni o ṣalaye pe ipa mani gbagbe ni orilẹ-ede yii ko ninu igbogunti imunilẹru awọn ọmọ ilẹ South Africa.

O sọ ọrọ naa nigba ti Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari lọ ṣe ayẹwo si i lori ọrọ ifiyajẹni ti wọn ṣe fun awọn ọmọ Naijiria.

Ramaphosa sọ wi pe, Ijọba ilẹ naa kẹdun iṣẹlẹ ikọlu naa lori bi o ṣe waye ni apa kan orilẹede oun ni bii ọsẹ meji sẹyin.

Buhari ati Ramaphosa

Oríṣun àwòrán, BASHIL AHMED

Àkọlé àwòrán, Ayesi fun Aare Buhari ni Papako Ofurufu

Aarẹ Ramphosa sọ ẹdun ọkan rẹ fun Aarẹ Buhari:

Aarẹ Ramaphosa fi kun ọrọ rẹ pe, Ijọba ilẹ naa yoo ri daju pe ofin ilẹ naa fi ese mulẹ fun tolori tẹlẹmu.

Aarẹ Ramaphosa wa fi da Buhari loju pe, South Afrika yoo ṣe ohun to yẹ lati mu ifẹ ati ajọṣepọ to dan mọnran ba ilẹ Adulawọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O tun ni pataki ẹtọ ọmọniyan ni orilẹ-ede naa yoo tẹ pẹlẹmọ ti yoo si bọwọ fun ofin.

O tẹsiwaju pe, ni bi ilẹ naa ti n ṣe ohun to yẹ lori eto ọrọ aje ati awujọ, ti o ṣe okunfa ibinu naa, sibẹ, wọn yoo dẹkun iwa rogbodiyan.

Ikini kaabo Aare Buhari

Oríṣun àwòrán, BASHIL AHMED

Àkọlé àwòrán, Ayesi fun Aare Buhari

Kini esi ti Buhari fun Ramphosa?

Lẹyin gbogbo atotonu Aarẹ Ramaphosa, Aarẹ Buhari ni ireti wa pe yoo ba awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Afrika sọrọ lori idojukọ wọn.

Ifiyajẹni lori awọn ọmọ Naijiria naa ti mu adinku de ba ibaṣepọ to wa laarin orilẹ-ede mejeeji.

Ṣugbon nigba ti Minisita fun ọrọ ilẹ Okeere ilẹ naa, Naledi Pandor n sọrọ pelu ojugba rẹ ti ilẹ Naijiria, Geoffrey Onyeama, o ni ko si ija rara laarin orilẹ-ede mejeeji.

Lati bii ọdun 1994 ni Naijiria ati Ilẹ South Afrika ti jọ ni aṣepo lori ọrọ Oṣelu, Ọrọ aje ati ọrọ ayika nigba ti wọn ṣe eto ibo akọkọ.

Lenu aipẹ ni ọga agba fun ọkọ ofurufu Air Peace, Allen Onyeama ṣe iranlọwọ kiko ọmọ Naijiria to to irinwo pada de latari ifiyajẹni naa .

Àkọlé fídíò, Òun tọjú àwọn ọmọ Nàìjíríà n rí ní South Áfríkà kọjá afẹnusọ

Ninu eyi to mu ki awon ọmọ Naijiria sọ wi pe ki Ijọba o tilẹkun mọ gbogbo ile iṣẹ ilẹ naa ni ilẹ yii.

Ninu atẹjade kan lati ile Ijọba ni wọn ti ni, ọna ti awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Afrika yoo ṣe maa gbe lai si ibẹru ni Aare yoo ba wọn sọ.

Àkọlé fídíò, Xenophobia: Naijiria á kọ́kọ́ pèsè ọ̀nà láti bá ẹbí sọ̀rọ̀ fún wọn

Aarẹ Buhari ni ọna ti aabo yoo fi wa fun dukia ati ẹmi wọn ni yoo ko ipa pataki ninu ipade ajọro naa.

Gẹgẹ bi ọrọ ti Aarẹ Ramaphosa sọ, o ni ipade oun ati Aare Buhari ni lati san okun ibaṣepọ aarin ilẹ mejeeji daaada.

Ati lati mu ifẹ ilẹ adulawọ dan mọnran si daadaa.

Ni kokari ọrọ wọn ni wọn si lọ tọwọ bọ iwe adehun laarin orilẹede mejeeji.

Àkọlé fídíò, Nigeria Independence Day: Wo ìlérí tí àwọn ènìyàn ṣe