Bangladesh wedding: Khadijah yí àṣà ìgbéyàwó padà ni Bangladesh

Aṣa to ti wa fun ọpọlọpọ ọdun ninu igbeyawo awọn eniyan Bangladesh ni Khadiza Akter Khushi yi pada.
Khadiza jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun ti o ti ni ifẹ Tariqul Islam lọkan ti pẹ.
O ko ọpọlọpọ ero sẹyin lọ si agboole ololufẹ rẹ nigba ti o fẹ dabi pe Tariqul ko fẹ tete gbe igbesẹ to yẹ fun igbeyawo.
Aṣa igbeyawo ni Bangladesh ni pe ki ọkọ iyawo ko ẹbi, ara ati iyekan rẹ sẹyin, ko gba agboole awọn iyawo rẹ to wuu lọ ki igbesẹ igbeyawo le bẹrẹ.
Khadijah lo yi aṣa yii pada pe oun fẹ ki awọn obinrin Bangladesh bọ ninu igbekun aṣa yii, paapaa awọn ti ololufẹ wọn ko yara ninu igbesẹ to yẹ fun iyawo.
Khadijah, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún tó kó àwọn ọgọ́rùn ún ènìyàn lọ sílé ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ láti ṣí ojú àwọn obìnrin sí àṣà yii.
Khadijah ṣalaye fawọn akọroyin BBC Bengali lẹyin igbesẹ rẹ yii pe: "Ohun to difa fawọn ọkunrin lati ko ero wa dẹnu ifẹ kọ awa obinrin ki a le ṣe igbeyawo naa lo difa fawa obinrin lati ṣe nkan kan naa".
O ni ìbí ko gbọdọ ju ibi nitori aṣa to fawọn ọkunrin lagbara lati dẹnu ifẹ kọ obinrin nigba ti o wu wọn naa lo yẹ ki obinrin ni lati dẹnu ifẹ kọ ọkunrin to wuu.
Khadiza ni oun ti woye pe kaka ki iya to n jẹ awọn obinrin dinku ni Bangladesh, niṣe lo n peleke sii nitori pe aṣa wọn fun ọkunrin ni agbara pupọ.
O ni mo gbe igbesẹ yii ki awa obinrin le bọ diẹ kuro ninu aṣa a n fogun ọdun duro de ọkunrin to nifẹ ẹ wa ṣugbọn ti ara kii ré lasiko'

Oríṣun àwòrán, AFP
Lọjọ Satide to kọja ni awọn lọkọlaya naa di ọkan ni ona ara ọtọ ni India.
Tariqul, ọkọ iyawo to jẹ ọmọ ọdun metadinlọgbọn sọ fun BBC pe lẹyin igbesẹ akin iyawo oun ni awọn ẹbi mejeeji pada wa fi tọwọtẹsẹ si igbeyawo awọn mejeeji.
O ni: ọpọ n ṣe igbeyawo wọn ninu kọọtu, awọn miran ni mọṣalaṣi ṣugbọn igbeyawo alaṣa ni awa ṣe.
A ni ọpọ ero ti iyawo mi ko lẹyin wa si agboole wa ti wọn duro bi o ṣoju mi fun igbeyawo nikẹyin.
Aṣa ati iṣe ninu igbeyawo ti Khadiza yipada:
Ninu aṣa igbeyawo Bangladesh, ọkọ iyawo ati ẹbi rẹ maa lọ si agboole iyawo nibi ti wọn yoo ti ṣeto igbeyawo.
Lẹyin igbeṣẹ ọkọ iyawo ati ẹbi rẹ ni iyawo yoo dagbere fun mọlẹbi rẹ ti yoo si gba ile ọkọ lọ.
Sugbọn ni agbegbe Meherpur ni iwọ oorun Bangladesh ni nkan ara ọtọ ti ṣẹlẹ.
Niṣe ni iyawo funra rẹ ko ero sẹyin to gba agboole ọkọ rẹ lọ bẹrẹ eto igbeyawo ara rẹ.
Leyin eto igbeyawo yii ni ọkọ iyawo ko lọ baa ninu ile rẹ.
Igbes'ẹ ọkọ iyawo yii ni ọpọ awọn ọkunrin ro pe ko dara rara pe o tako aṣa akọ.
Awọn miran gan an a ni ohun ti eti ko gbọri ni bi iyawo ṣe ko ero sẹyin wa sile ọkọ fun eto igbeyawo funra rẹ.
Opọ so fun BBC pe iru rẹ ko ṣẹlẹ ri nigboro ki a to ṣẹṣẹ wa sọ pe ni abule ni Bangladesh.
Koko kan ti gbogbo eeyan gba ni pe tọkọtaya yii ti gbe igbesẹ akin ni eyi ti wọn fi tẹ ifẹ ara wọn lọrun.
Lẹyin igbeyawo yii ni iyawo ti sọ fun awọn obinrin Bangladesh lati jade gbe igbesẹ to yẹ ki wọn fi yanju ohun to ba wu wọn lọkan.
Bayii, ayipada ti n de ba ero ati ihuwasi awọn obinrin ẹkun yii.
Won ti n gbe igbesẹ akin to jẹ pe okunrin nikan lo n gbe tẹlẹ ni ẹkun yii.
Awọn musulumi lo pọ ju ni agbegbe yii ni eyi ti ko fi kọkọ rọrun ki obinrin da ni ominira ṣugbọn ajọ isọkan agbaye United Nations ni iyatọ ti n wa sii bi olaju ṣe n de ibẹ sii.
Bayii, ọpọ awọn obinrin wọn lo ti n kawe sii ju ti tẹlẹ lọ ni eyi to ti n jẹ ki awọn obinrin yẹ awọn ofin igbeyawo ti ko fun wọn layọ wo.
Ọpọ awọn ẹgbẹ ajijangbara fobinrin lo ti n dide ni ẹkun Bangladesh bayii.
Tokọtaya Tariqul ati Khadijah ti gba pe igbesẹ ti wọn gbe ninu igbeyawo wọn yii yoo mu itẹsiwaju ba ominira awọn eniyan Bangladesh.
Ati pe obinrin yoo tun ni agbara sii lati gbe igbesẹ to ba wuu.
Awọn mejeeji sọ fun BBc pe pẹlu idunnu ati ayọ ni awọn fi ṣeto igbeyawo naa.

















