Cardless Withdrawal: Èyí ni àwọn ìlànà tí o le fi gbowó ní ATM láì lo káàdì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laipẹ yii ni iroyin gbe iṣẹlẹ kan to waye niluu Ibadan nibi ti awọn araalu ti lu arakunrin kan ni adugbo Dugbẹ nitori pe wọn ri t'oun gba owo lẹnu ẹrọ 'ATM' lai lo kaadi.
Eyi jẹ iyalẹnu fun awọn eniyan wọnyii ti ko mọ pe iru eto bẹ ẹ ti wa, ti o si ṣeeṣe ki wọn l'ero pe onijibiti ni ọkunrin naa.
Koda, wọn ko lu u nikan, niṣe ni wọn tun fa a le ọlọpaa lọwọ gẹgẹ bi arufin.
Ṣugbọn ṣa, eto imọ ẹrọ̀ gbigba owo l'ẹnu ATM lai lo kaadi ti wa ni orilẹ-ede Naijiria lati ọdun 2014.
Igba naa si ni awọn onibara ileefowopamọ kan ti n lo o. Amọ, o da bi ẹni pe ọpọ ọmọ Naijiria ni ko ti i gbọ tabi mọ nipa ilana tuntun yii.
Imọ ẹrọ tuntun naa wulo lasiko ti o ba gbagbe tabi ti o ko ba mu kaadi ATM rẹ dani, ti o si nilo owo pajawiri.
O le tẹle awọn ilana yii lati bẹrẹ si ni i lo ilana tuntun naa.
- Lori 'App' ileefowopamọ to wa lori ẹrọ ibanisọrọ alagbeka rẹ, tẹ 'Cardless Withdrawal' lara awọn igbesẹ ti o ba gbe wa fun ọ.
- Ranti lati tẹ ẹ boya ẹka ileefowopamọ rẹ lo ti fẹ gba owo tabi ileefowopamọ mii.
- Dahun gbogbo ibeere ti oju-ewe naa ba gbe wa fun ọ.
- Ki o si tẹ 'pin', iyẹn numba mẹẹrin ti oun lo fun 'App' naa.
- Lẹyin gbogbo igbesẹ yii, ileefowopamọ rẹ yoo fi awọn numba kan ranṣẹ si ori ẹrọ ibanisọrọ alagbeka rẹ. Numba yii ni o lo nidi ẹrọ ATM.
- Nidi ATM wayi, tẹ 'Enter' lara awọn bọtinni to wa lara ATM naa.
- Ki o si mu 'Cardless Withdrawal' lara awọn igbesẹ ti o ba gbe wa fun ọ.
- Tẹ awọn numba ti wọn ti kọkọ fi ranṣẹ si ọ.
- Tẹ iye owo ti o fẹ ẹ gba ( Eyi ko gbọdọ yatọ si iye ti o ti kọ tẹlẹ nigba ti o bẹrẹ igbesẹ naa lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ).
- Tẹ 'Enter' lati tẹsiwaju.
- Gba owo rẹ.
Lati gba owo ni ileefowopamọ ti kii ṣe tiẹ:
- Nidi ATM wayi, tẹ 'Enter' lara awọn bọtinni to wa lara ATM naa
- Mu 'PayCode' lara awọn igbesẹ ti o ba gbe wa fun ọ
- Tẹ numba 'PayCode' ti wọ̀n ti kọkọ fi ranṣẹ sori ẹrọ ibanisọrọ rẹ
- Tẹ iye ti o fẹ gba ( Eyi ko gbọdọ yatọ si iye ti o ti kọ tẹlẹ nigba ti o bẹrẹ igbesẹ naa lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ)
- Tẹ 'Enter' lati tẹsiwaju
- Gba owo rẹ
Yatọ si pe o le bẹrẹ igbesẹ naa pẹlu 'App' lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ, o tun le lo awọn aṣayan numba ti ileefowopamọ rẹ n lo lati fun ẹrọ ibanisọrọ (Fun apẹẹrẹ *111#).
Lẹyin naa, tẹle awọn igbesẹ ti o ba yẹ
Yatọ si 'Cardless Withdrawal, awọn ọrọ ti awọn ileefowopamọ tun maa n lo ni Cash-on-The-Go, Dial4Cash, Magic Cash, ati bẹẹbẹ lọ.
















