Alasiya Lagos Killing: Oun tójú àwọn ará àdúgbò rí nìyìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ara adugbo Alasiya kan nibi ti iṣẹlẹ ẹsun pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun kan bẹ ori eniyan mẹta ni agbegbe naa ti ṣẹlẹ ni oun gbọ ọpọlọpọ iro ibọn lọganjọ oru.
Iwadii fihan wi pe daju daju, eniyan marun un ni wọn da ẹmi wọn legbodo ni Abraham Adesanya Estate, ijọba ibilẹ Eti Ọsa ni ilu Eko loru ọganjọ ọjọ aiku to kọja yii.
Black Che to jẹ ọmọ ipinlẹ Enugu ni inu ile iṣẹ ni awọn wa loru ọjọ ti ibọn n ro, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi jade sita lowurọ, oku eniyan marun un ni wọn ba nilẹ.
"Meji ninu awọn oku yii ti mo ri ni wn ge ori wọn, wọn yin ọkan ni ibọn ti wọn si fi abẹ la ọrun rẹ. Wọn ṣa omii ni ada ti wọn si tun ṣa èyi to kù wẹlẹ wẹlẹ. Kaakiri agbegbe ibudokọ Alasiya ni wọn pin awọn oku naa si.
Wọn ni "awọn ọlọpaa gbe oku oku mẹrin kuro ṣugbọn mọlẹbi ọkan to ku ko yọnda rẹ nitori wọn ko gba wọn laye lati gbe e lọ. Iṣẹlẹ naa ba ni lẹru jọjọ"
Bakan naa, aṣọna kan ni adugbo naa, Kalu Uka ni bi oun ṣe gbọ ibọn lọwọ oru, kia kia l'oun ti ilẹkun ita ile iṣẹ ti wọn gba oun lati maa ṣọ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun un lati gbọ iku eniyan marun un lowuro ọjọ keji.
Ẹwẹ, nigba ti BBC Yoruba kan si ile iṣẹ ọlọpaa, ohun ti awọn ọlọpaa fọ ni wi pe awọn n se iwadii kikun lati ri aridaju boya awọn ẹgbẹ okunkun lo ṣe iṣ laabi yii tabi bẹẹ kọ.













