NSCDC/Police Clash: Ìwádìí nípa ikú òṣìṣẹ́ NSCDC tí ọlọ́pàá lù níwájú ìyàwó àti ọmọ ti jáde

oṣiṣẹ NSCDC Ochigbo Ogah ati ibi ti awọn ọlọpaa ti mu

Lẹyin ọ̀sẹ mẹ́rin ti iròyìn kan bi awọn ọlọ́pàá Nyanya nilu Abuja ṣe mu oṣiṣẹ NSCDC kan, Ochigbo Ogah, fun riru ofin oju popo, ti wọn si lu u titi ti wọn fi wọ ọ lọ agọ wọn nibi to ti gbẹmi mi, iwadii ti fi han wi pe, ṣe ni ẹjẹ da si i ni ọpọlọ lẹyin ti wọn fi nkankan lu u lori.

Lẹyin ti gbogbo ọmọ Naijira bẹnu atẹ lu bi awọn ọlọpaa ṣe lu arakunrin naa, ni wọn ṣe ayẹwo oku rẹ.

Ayẹwọ naa ti o tẹ awọn oniroyin lọwọ fi han wi pe ko si aisan kankan lara arakunrin naa ki o to ku lojiji lẹyin iṣẹlẹ pẹlu awọn ọlọpaaa naa.

Iroyin yi n jade lẹyin ti agbẹnusọ ọlọpaa ni Naijiria, Frank Mba ni ko si oun kankan to ṣe Ogah ati wi pe, ṣe ni o funra rẹ wa ọkọ rẹ wa si agọ ọlọpaa Nyanya ki o to gbẹmi mi. Mba sọ nigba naa wi pe ko si ootọ kankan ninu iroyin wi pe awọn ọlọpaa lu u ni alubami.

Ibi ibudo awọn ọlọpaa to n dari ọkọ ni popona Nyanya-Karshi ni bi aago meje aabọ ogunjọ oṣu kẹta ni iṣelẹ naa ṣẹlẹ. Iyawo rẹ sọ fun awọn oniroyin wi pe nigba ti wọn mu ọkọ oun, oun ati ọmọ oun wa nibẹ.

O ṣalaye wi pe, ṣe ni wọn fi kóńdó ọlọ́pàá náà lori ati lara. Esi ayẹwo ile iwosan lori oku Ogah fi han wi pe, lẹyin lilu ti wọn lu oloogbe naa, ọpọlọ rẹ wu. Wọn ni oun to pa ree.

Akọroyin BBC Yoruba kan si Mba lati gbọ oun to nii sọ nipa esi ayẹwo yii ati igbesẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa fẹ gbe lori ọrọ naa. Ṣugbọn oluranlọwọ rẹ kan sọ wi pe, o wa ninu ipade, ati wi pe irọle ni yoo le ba akọroyin naa sọrọ.

Àkọlé fídíò, Segalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ