Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tún ti ṣèlérí àtúntò ikọ̀ ọlọ́pàá kògbérégbè FSARS

Aworan ọlọpa SARS kan

Oríṣun àwòrán, @OfficialSARS

Àkọlé àwòrán, Àwọn aláṣẹ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìlànà iṣẹ́ ikọ̀ ọlọ́pàá kògbérégbè FSARS kò fi ààyè ìrégbè sílẹ̀ fún wọn

Ileeṣẹ ọlọpa ti ni ko si ofin kan to fun awọn oṣiṣẹ ọlọpa FSARS lati da ọkọ duro fun ayẹwo loju popo.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Edo, Haliru Gwandu lo ṣalaye ọrọ yii lasiko ifọrọwerọ lori ikanni ayelujara twitter kan to waye lori ọrọ awọn ọlọpa SARS.

Ifọrọwerọ ori ikanni ayelujara Twitter naa ti wọn pe ni #AskThePolice #ReformSARS ni wọn gbe kalẹ lati fun araalu ni anfani lati fi ẹhonu wọn han lori ise awọn ọlọpa FSARS lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gwandu to jẹ kọmisọna ọlọpaa ni Edo ni lootọ ojuṣe ọlọpa labẹ ofin ni lati daabo bo araalu, ṣugbọn eredi idasilẹ ikọ kogberegbe FSARS ni lati da si ipe 'gbami-gbami' araalu.

"Iṣẹ pọ lọrun ikọ ọlọpa FSARS, lati koju iwa idigunjale, ijinigbe, jiji ẹran ọsin gbe atawọn iwa ipa gbogbo

Ko si ẹni to ran awọn ọlọpa ikọ naa lati maa da ọkọ duro tabi ṣe ayẹwo ọkọ"

Gẹgẹ bii ọga ọlọpa naa tun ṣe tẹẹ si oju ikanni Twitter, o ni ''ko si ilana iṣẹ awọn ọlọpa ikọ FSARS to fun wọn lagbara tabi aṣẹ lati mu alaiṣẹ''.

Gwandu ni gbogbo ẹhonu araalu ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpa yoo mojuto ni ibamu pẹlu ipinnu ọga agba awọn ọlọpa lati mu atunto ati atunṣe ba ikọ ọlọpaa kogberegbe FSARS lati lee bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ wọn bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.