#justiceforstephen: Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó láwọn ti mú afunrasí méjì tó mọ̀ nípa ikú Dókítà Stephen Urueye

Oríṣun àwòrán, Stephen Urueye/Facebook
Ile iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti kede pe awọn ti mu afunrasi meji ti o lọwọ ninu bi awọn kan ṣe gun dokita kan ni ọ̀bẹ pa ni ile ẹkọ iwosan LUTH niluu Eko.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Bala Elkana lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun akọroyin BBC to n tọ pinpin iṣẹlẹ yi.
Dokita Stephen Urueye to jẹ akẹkọọ imọ iṣegun oyinbo lo n ṣiṣẹ pẹlu ile ẹkọ iwosan LUTH nilu Eko, ko to o padanu ẹmi rẹ lẹyin ti awọn eeyan kan gun ni ọbẹ pa.

Alukoro ọlọpaa sọ pe''niṣe ni dokita naa ati awọn ọrẹ jade faaji lalẹ Ọjọb, ki awọn janduku to pade wọn ti wọn si da ọgbẹ si lara lẹyin ti wọn gba dukia wọn.
Iṣẹlẹ yi mu ki awọn dokita to jẹ akẹkọọ bẹrẹ iwọde lati fi ẹhonu han lori iku rẹ.
Lasiko iwọde naa ,wọn kesi ijọba lati pese aabo to peye nitori pe ''eyi ki ṣe igba akọkọ ti awọn janduku yoo kọlu awọn akẹkọọ dokita lagbegbe naa.


Dr Ureya to kẹkọ imọ iwosan ati iṣẹ abẹ la gbọ pe o ku lẹyin ọjọ meji to gba iwe ẹri moyege ẹkọ.









