Kọmisọnà ọlọ́pàá ni àwọn yóò tú iṣu dé ìṣàlẹ̀ ìkòkò lóri ọ̀rọ̀ náà

Àkọlé fídíò, Okùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti sàfihan àwọn ti wọn fẹ̀sun kan pé wọn yìbọn pa Kolade Johnson laja ìsìnmi tó kọja.

Wọn ní àwọn afunrasi náà ni insipẹkitọ Olalekan Ogunyemi àti Godwin Orji ti wọn ń siṣẹ́ pẹ̀lú ẹka to ń gbógun ti ìwà ẹgbẹ́ okunkun àti ìdigunjale.

Lóri òpó twitter ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ni wọn ti kédé wọn ti wọn si ni wọn o fi wọn jófin lábẹ ìdájọ ododo.

Kọmisọna ọlọpàá ìpínlẹ̀ Eko Zubairu Muazu náà ṣe àbẹwo si ilé ọlọogbe to si fi dáwọn lóju pé ẹlẹ́sẹ̀ kan ò ni lọ láìjìyà.

Awọn obi Kolade

Oríṣun àwòrán, Policeofficial

Àkọlé àwòrán, Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti dárúkọ àwọn SARS to pa Kolade

Abiyamọ ìyá olóògbé tí SARS yìnbón pá fàwọ́n lé kóòtù Olorun

Obi Kolade Johnson ti SARS yìnbọn pa ni ìpínlẹ̀ Eko ti ké gbàjarè pé kijọba ṣe ohun tó yẹ́ fún SARS tó gbẹ̀mí ọmọ wọn.

BBC Yoruba ba baba oloogbe Kolade Johnson sọrọ lori ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ wọn.

Iyaafin Olufunkẹ Ọdẹbiyi to jẹ iya oloogbe ṣalaye fun BBC pé, ko sẹni to lé mu awọn SARS to pa ọmọ oun, ayafi Olodumare.

O ni adura oun ni pé ki Olorun gbẹsan ikú ọmọ oun alaiṣẹ.

Awọn aladugbo ti ọrọ naa ṣoju wọn ni idije bọọlu alafẹsẹgba laarin Liverpool ati Tottenham ni oloogbe wa wo nile ijẹun adugbo ki ọlọjọ to de.

Wọn ni awọn SARS naa ti pinnu lati gba ẹjẹ eeyan ninu ọrọ ẹnu wọn bi wọn ṣe de adugbo naa tẹlẹ.

Koda wọn ni oju ara nkan ọmọkunrin Kolade ni ibọn ikẹta ti ọlọpàa SARS naa yin ti baa ko to ku ki wọn to gbee de ilé iwosan

Egbọn oloogbe ni idojukọ ikorira Xenophobia to ṣẹlẹ ni South Africa lo jẹ ki Kolade wale lati ibujoko rẹ.

O ni ko sẹni to mọ pé iku ti fẹ mu akẹkọọ jade fasiti ti ilu Benin ti a mọ si UNIBEN naa lọ lọwọ ibọn SARS laiṣẹ.

Alhaji Remi Lukman to bi oloogbe naa ṣalaye pé ọfọ nla lo ṣẹ oun ati pe ki ijọba gbe igbesẹ to yẹ kiru eyi maa ṣẹlẹ mọ sawọn alaiṣẹ.