Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nilẹ̀ Adulawọ lọṣẹ tó lọ

A ni ki a fi eleyi ṣe moriwu fun yin nibẹrẹ oṣu tuntun ki a si ma gbagbe awọn ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to pari oṣu ti a lo tan.

Diẹ ree ninu akojọpọ awọn awọran manigbagbe lati ilẹ Áfríkà lose to kọja fun igbadun yin.

Aworan awọn obinrin ni Mozambique to n to lati gba nnkan elo lọjọ Iṣẹgun ni Estaquinha, Mozambique, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan ti iji Cyclone Idai ṣe akoba fun ko tii bọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun. Awọn obinrin wọnyi ni Mozambique n to lati gba nnkan eelo lọjọ Iṣẹgun to kọja.
Aworan awọn ọmọbinrin to n ṣa ododo nibi awọn ile ti o wo ni ilu Beira lọjọ aiku.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iya n ronu; ọmọ n roka lo ri ni Mozambique. Bi awọn iya ti ṣe n to lawọn ọmọdebinrin wọnyi n ṣa ododo nibi awọn ile ti o wo ni ilu Beira lọjọ Aiku.
Aworan awọn ọmọkunrin to n ṣere lori igi agbọn ti iji wo ni Beira lọjọru

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jangilofa epo mọtọ! Nilu ti iji ti sọṣẹ niṣe ni awọn ọmọkunrin wọn yi n ṣere lori igi agbọn ti iji wo lọjọru
Peter Mokaya Tabichi nibi ti awọn akẹkọọ rẹ ti n ki kaabọ lati Duba ni papakọ ofurufu Jomo Kenyatta lọjọ kẹtadinlọgbọn, osu kẹta

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Lorile-ede Kenya, awọn akẹkọọ da muso fun olukọ wọn ni papakọ ofurufu Kenya nigba to dari lati ibi ti o ti gba ẹbun $1m (miliọnu dọla kan) gẹgẹ bi olukọ to pegede julọ lagbaye
Aworan igbakeji aarẹ Naijiria Yemi Osinabjo lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta ọdun 2019 nilu Ikenne,Ipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, @ProfOsinbajo

Àkọlé àwòrán, Igbakeji aarẹ Naijiria ati iyawo rẹ, Dolapo Osinbajo nibi ayẹyẹ isin idupe lẹyin ti wọn wọle gẹgẹ bi igbakeji aarẹ nidibo Naijiria tó kója nilu Ikenne, ipinlẹ Ogun
Aworan alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Zimbabwe to n dawọ idunu ni papa iṣere nla Harare lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta ọdun 2019.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Lọjọ Aiku, alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Zimbabwe yi n dawọ idunnu bi ikọ rẹ ti ṣe fi ami ayo 2-0 sagba Congo-Brazzaville ninu ifẹsẹwọnsẹ lati kopa ninu idije Africa Cup of Nations
Aworan ajagunfẹyinti orileede Ethiopia to n fẹsẹ rajo nibi ayẹyẹ kan ti wọ́n lati fi gba alejo irun ori Emperor Tewodros II lọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹta ọdun 2019

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Lọjọ Abamẹta, ajagunfẹyinti orile-ede Ethiopia yi n fẹsẹ rajo nibi ayẹyẹ kan ti wọn ṣe lati fi gba alejo irun ori Emperor Tewodros II ti ile iṣẹmbaye ilẹ Gẹẹsi, National Army Museum da pada si Ethiopia
Aworan oludibo to n yẹ orukọ rẹ wo loju patako lati le kopa ninu idibo aarẹ Comoros islands

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Lọjọ keji, oludibo yi n yẹ orukọ rẹ wo loju patako lati le kopa ninu idibo aarẹ Comoros Islands
Aworan awọn eeyan Algerian to n kopa ninu iwọde lọjọ kejilelogun, oṣu kẹta nilu Algiers eleyi to fẹ ki aarẹ Abdelaziz Bouteflika kọwe fipo silẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Fọfọ ni igboro Algiers kun nibi iwọde to waye lọjọ Eti. Awọn eetan orile-ede naa fẹ ki aarẹ Abdelaziz Bouteflika kọwe fipo silẹ
Aworan awọn eeyan Algerian to n kopa ninu iwọde lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹta nilu Algiers eleyi to fẹ ki aarẹ Abdelaziz Bouteflika kọwe fipo silẹ

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Titi di ọjọ Ajẹ awọn eeyan Algeria ko dawọ iwọde naa duro