Àwọn agbófinró ń wá ọlọ́pàá tó yìnbọn lu olólùfẹ̀ẹ́ méjì, lẹ́yìn tí wọ́n gbé akẹgbẹ́ẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Segalink
Ajọ ọlọpaa Ipinlẹ Eko ti kede orukọ awọn ọlọpaa to lọwọ si bi wọn ṣe yinbọn lu awọn ololufẹ meji ni Ajegunlẹ ni ipinlẹ naa, ti arabinrin naa si gbẹmii mi.
Awọn ọlọaa naa ni Insipekitọ Adamu Usman, Sajẹnti Adeyeye Adeoye, Sajẹnti Kashim Tijani, Sajẹnti Lucky Akigbe ati Sajẹnti Paul Adeoye.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Eko, Bala Elkana ni awọn ọlọpaa naa ti n jẹjọ bayii bi kọmiṣọna ọlọpaa Zubairu Muazu si ṣe pàṣẹ pe ki wọn wa ọkan lara wọn, Insipekitọ Dania Ojo, to fẹsẹ fẹ lẹyin ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Bi iroyin ọrọ naa ṣe kan kakakiri ni awọn ọmọ Naijiria ti fi ẹhọnu wọn han lori ẹrọ ayelujara.
Iroyin ni ṣe ni awọn ọlọpaa le ọrẹkunrin ati ọrẹbinrin naa nigba ti wọn n bọ lati ile igbafẹ kan ni agbegbe Ajegunlẹ ni ipinlẹ Eko. Nigba ti ọwọ wọn ko tete tẹ wọn, awọn ọlọpaa yinbọn lu wọn.
Arabinrin ọmọ ọgun ọdun naa, Ada Ifeanyi, si ku loju ẹsẹ ti ibọn ọlọpaa báa.
Lẹyin ti iroyin ni awọn ọlọpaa ṣe ikọlu si wọn, ni a ti gbọ pé ọrẹọkunrin rẹ, Emmanuel Akomafuwa, naa si wa ni ile iwosan lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Iroyin ni awọn ololufẹ mejeeji naa n bọ lati ibi igbafẹ ni ki wọn to koju awọn ọlọpaa ninu eyi ti ẹmi ọmọbinrin naa ti bọ́ si.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2
Ninu aworan ti wọn fi lede ni obinrin naa ti n jẹ irora nilẹ, ko to di wi pe o papoda.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

End of X post, 4
Ọmọ Naijiria pẹlu ibinu ni awọn fi n fi ẹhọnu han lori ẹrọ ayelujara Twitter wọn lori ẹsun pe awọn ọlọpaa ko bikita nipa ẹmi awọn eniyan.
Ni bayii, iroyin fihan pe ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti fi panpẹ ọba mu awọn ọlọpaa ti wọn fi ẹsun kan naa, ati wi pe iwadii n tẹsiwaju.
Gbogbo igbiyanju BBC lati beere sii nipa awọn ti iroyin ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ko tii bi eso ti a n fẹ lọwọ.