APC sí Atiku: Kò tọ́ sí Atiku láti du ìpò nítorí ọmọ Cameroon ni

Aarẹ Buhari ati Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Buhari ati Atiku Abubakar

Oludije lẹgbẹ oselu PDP ninu idibo si ipo aarẹ to kọja, Atiku Abubakar ti ni ọmọ Naijiria lọọtọ ni oun, ati wi pe ọrọ ẹgbẹ oselu APC ko ja mọ nkankan.

Atiku sọ eyi lasiko to n fesi ọrọ ti ẹgbẹ oselu APC sọ wi pe ko tọ ọ si lati dije dupo aarẹ lorilẹede Naijiria nitori ilẹ Cameroon lo ti wa, ti kii si i se ọmọ Naijiria.

Oludije lẹgbe oselu PDP wa ni ara lo n ta ẹgbẹ oselu APC ati wi pe agbẹjọrọ oun ni ẹlẹjọ wọn ni ile ẹjọ.

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lo fi ọrọ lede wi pe oludije fun ẹgbẹ oṣeluPeoples Democratic Party (PDP), Atiku Abubakar kii ṣe ọmọ bibi orilẹede Naijiria.

Eyi lo n fa ibeere ati ọpọlọpọ esi ti awọn ọmọ Naijiria n fi sita lori ẹrọ ayelujara lati igba ti ọrọ yii ti ti ẹnu ẹgbẹ oṣelu APC jade si Atiku Abubakar.

APC ni aridaju akọsilẹ wa pe ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 1946 ni wọn bi Atiku Abubakar ni ilu Jada ni Adamawa, iha ariwa Cameroon.

Àkọlé fídíò, Bí o ṣe lè fí òǹkà, ọ̀mọ̀ ìka tàbí ìkúùkù wọn oúnjẹ́

APC ni nitori eleyii, ipẹjọ ti Atiku Abubakar fi sọwọ si ile ẹjọ to n gbọ ẹsun awọn to di ipo nla mu ko lẹ nilẹ ati pe ko tilẹ tọ si Atiku lati du ipo ninu idibo orilẹede Naijiria nitori ọmọ orilẹede Cameroon ni.

Ajọ INEC kede aarẹ Buhari gẹg bi ajawe olubori plu ibo 15,191,847 eyi to fi fi ẹyin alatako rẹ, Atiku janlẹ to ni ibo 11,262,978 ṣugbọn ṣe ni Atiku kọjalẹ to si pe ẹjọ lori pe oun lo yẹ ko jawe olubori.

Àkọlé fídíò, Ọ̀dọ́kùnrin tó kọ́kọ́ ṣe ẹ̀rọ tó ń tu ìyẹ́ lára adìyẹ

Wọn ni igba awọn oyinbo amunisin, orilẹede Germany lo n dari orilẹede Cameroon nigba naa ko to di ẹyin ogun ti orilẹede naa yapa. Ilẹ Faranse n dari apa kan nigba ti ilẹ Gẹẹsi n dari apa keji labẹ akoso Naijiria.

Wọn ni eyi ja si wi pe ọdun 1961 ni apa ibi ti Atiku Abubakar ti wa dara pọ mọ orilẹede Naijiria.

"Nitori naa a duro lori pe gbogbo ibo ti Atiku ni lasiko idibo, ofo lasan ni". Ṣugbọn ibo ti oludije wa daju ko si si eru ninu idibo naa" gẹgẹ bi APC ṣe sọ ọ ninu esi wọn.