Buhari: Mo ní ìrètí pé àwọn ọmọ Chibok yóò padà wálé

BUHARI

Oríṣun àwòrán, @BUHARI

Àkọlé àwòrán, Ọjọ́ Kẹrinla, Osu Kẹrin, ọdun 2019 lo pé ọdun márùn ún tí ikọ̀ Boko Haram jí àwọn ọmọ ilé ìwé Chibok gbé.

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ fun awọn ẹbi awọn ọmọ ile iwe awọn obinrin Chibok ni ilu Borno wi pe oun ko gbagbe awọn ọmọ naa to wa ni igbekun Boko Haram.

Ọjọ Kẹrinla, Osu Kẹrin, ọdun 2019 ni ọdun marun ti ikọ Boko Haram ti ji awọn ọmọ ile iwe Chibok gbe ni ile iwe wọn ni ọdun 2014.

Aarẹ Buhari seleri fun awọn iya ati baba awọn ọmọ Chibok naa wi pe oun yoo ri daju wi pe awọn ọmọ Chibok yoo pada wale lalaafia.

Biotilejepe awọn ọmọ ile iwe Chibok ọgọrun ati meje ni wọn ti gbaalẹ ni panpẹ awọn ikọ Boko Haram lati bii ọdun mẹrin sẹyin, Aarẹ Buhari ni oun ko ni sinmi titi awọn ọmọ naa yoo fi pada sọdọ awọn obi wọn.

Àkọlé fídíò, Bí o ṣe lè fí òǹkà, ọ̀mọ̀ ìka tàbí ìkúùkù wọn oúnjẹ́

Bakan naa ni Aarẹ Buhari fi kun wi pe ijiroro naa n lọ lori Leah Sharibu ti ikọ Boko Haram naa jigbe ni ile iwe rẹ ni Dapchi ni ipinlẹ Yobe ni Ọjọ Kọkandinlogun, Osu Keji, ọdun 2018.