Oladejo Okediji, gbajúgbajà òǹkọ̀wé Yorùbá papòdà lẹ́ni ọdún 89

Oríṣun àwòrán, Oladejo Okediji/Facebook
Ọpọ àwọn eniyan Naijiria lo n ṣe ilede lẹyin Oloogbe Oladejọ Okediji.
Lonii ni Oloogbe Oladẹjọ Okediji to jẹ ogbontarigi agba onkọwe lede Yoruba ko ba pe ẹni aadọrun un ọdun loke eepẹ.
Oladẹjọ ni awọn kan n pe James Hadley Chase ti iran Yoruba fun awọn iwe ọdaran to n munilọkan loriṣiiriṣii to ti kọ sẹyin.
Bẹẹ, ti onirese ko ba fingba mọ, eyi to ti fin tẹlẹ ko ni bajẹ layelaye.

Oríṣun àwòrán, @others

Oríṣun àwòrán, @others
Onigege wura ni ọgbọn ikọwe Okediji dabi ki a da ti ọpọ agba ọjẹ onkọwe papọ ni
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Dele Momodu, ọkan lara awọn to kọkọ ṣọfọ agba ọjẹ onkọwe yii lori ayelujara ni o ku diẹ ki baba pe aadọrun pẹlu awọn apẹẹrẹ iwe to ti kọ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Die lara awọn aworan lasiko isinku Baba Oladejọ Okediji ni Oyo:

Oríṣun àwòrán, @Rebecca

Oríṣun àwòrán, @Rebecca

Oríṣun àwòrán, @Rebecca

Oríṣun àwòrán, @Rebecca

Oríṣun àwòrán, @Rebecca

Oríṣun àwòrán, @Rebecca
Oladejo Okediji àti ìgbé ayé ìtàn kíkọ rẹ̀
Ìlúmọ̀ọ́ká òǹkọ̀wé Yorùbá bàbá Oladejo Okediji ti rèwàlẹ̀ àsà, ìdájí Ọjọ́rú ni bàbá tẹ́rí gbaṣọ.
Gbajugbaja ni oloogbe onkọ̀we Oladejo Okediji jẹ larin awọn onkọ́we Yoruba ọmọ orilẹ-ede Naijiria.
Ninu ifọrọjomitoro ọ̀rọ̀ kan pẹlu rẹ nigba aye rẹ eleyii ti aṣewadii ijinlẹ kan ninu imọ Litiresọ ilẹ Afirika, Karin Barber ṣe, awọn ohun iyalnu ni iru iṣẹ́ ti oloogbe yii ti ṣe silẹ ko to lọ.
Bakan naa, ifọrọjomitoro ọ̀rọ̀ naa sawari nipa iru eniyan ti Oladejo jẹ, itan igbesi aye rẹ to fi mọ irufẹ ọna ti oun gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ onkọwe ọmọ il adulawọ n gba kọ awọn itan rẹ.
Diẹ lara awọn nkan ti o da yatọ nipa oloogbe Oladejo ree.
- Aṣaju ni Oladejo jẹ ninu kikọ iwe arosọ ati iwe ere to da yatọ pẹlu ọna ti o n gba lo ede ilẹ Afirika ninu itan rẹ.
- O ti kọ ọpọlọpọ arosọ, iwe akagba to fi mọ iwe itan kekeeke lede Yoruba.
- Oladejọ naa ti ni ipenija nipa yiyi ede kan pada si omiiran bẹ́ẹ̀ si ni oun naa ti ni iriri tirẹ pẹlu awọn ontẹwe.
- Ohun to saba maa n bi itan kikọ rẹ ni bo ṣe n ri lojoojumọ ninu igbe aye awọn ara Iwọ Oorun Afirika.
- Bi nkan ṣe ri gẹlẹ, nigba mii ẹfẹ, ọrọ to le koko ati bẹẹ bẹẹ lọ a maa jẹyọ ninu itan rẹ.
- Iwe arosọ meji to kọkọ kọ ni Aja lo lru (1969) ati Agbalagba Akin (1971).
- Awọn iwe mii to ti kọ to gbajumọ ni Atoto Arere (1981), Rẹrẹ Run (1973).















