Oladejo Okediji, gbajúgbajà òǹkọ̀wé Yorùbá papòdà lẹ́ni ọdún 89

Oladejo Okediji

Oríṣun àwòrán, Acebook/Oladejo Okediji

Àkọlé àwòrán, Iku mu ẹni re lọ

Iku doro, iku ṣe 'ka, iku mẹ'ni 're lọ. Gbajugbaja onkọwe lede Yoruba Oladejo Okediji ti papoda lẹni ọdun mọkandinlaadọrun un.

Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe ti orukọ rẹ n jẹ Goke ṣalaye pe idaji owurọ Ọjọru ni ẹlẹmi gbaa ti baba rewalẹ asa.

Iroyin sọ pe ọgọrọ eeyan lo lu ile baba to wa ni Mobolaje niluu Oyo pa nipinlẹ Oyo lati kẹdun ẹni 're to lọ.

Àkọlé fídíò, Hakeem: Mo lè sọ arúgbó dí ọmọge nígbà tó bá wù mí

Diẹ lara awọn iwe ti oloogbe Okediji kọ nigba aye rẹ ni Aja Lo Leru, Rere Run, Agbalagba Akan, Atoto Arere, ati Karin Kapo.

Awọn iwe miran ti oloogbe kọ ni Opa Agbeleka, Oga Ni Bukola, Sango, Iroyin Ayo, Binu Tiri ati, Aajo Aje.