Buhari: Ìkọlù Fulani àti ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ní Kaduna àti Rivers burú jáì

Oríṣun àwòrán, Presidency
Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu laarin awọn Fulani ati awọn eeyan lawujọ Adara ni ipinlẹ Kaduna.
Ogun eeyan lo di oloogbe latipasẹ akọtun ikọlu miran to waye lọsan ọjọ isẹgun.
Aarẹ Buhari to fọrọ naa lede lati ẹnu oluranlọwọ rẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu, wa rọ awọn eeyan Adara ati awọn Fulani lati faye gba alaafia laarin wọn.
Bakan naa, Aarẹ Buhari koro oju si bi awọn ẹlẹgbẹ okunkun ti n fẹmi awọn eeyan ṣofo nipinlẹ Rivers.
Aarẹ rọ awọn eeyan nipinlẹ Rivers lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro ki wọn le dẹkun awọn ẹlẹgbẹ okunkun to n yọ ipinlẹ naa lẹnu.
Aarẹ Buhari rọ awọn ọmọ Naijiria ni gbogbo ipinlẹ lati yago fun iwa bi adiẹ ba dami loogun nu, maa fọ lẹyin ti ede-aiyede ba bẹ silẹ laarin wọn.
Aarẹ tun rọ awọn olori ẹsin ati awọn ọba alade lati rii wi pe ọrọ ti yoo mu alaafia jọba, ni wọn n sọ jade lẹnu.









