Rélùwéè Eko: Alágbe tó kú náà jẹ́ ara àwọn tó ń jókòó lẹ́bàá ojú ìrìn

Ọkọ Oju irin

Oríṣun àwòrán, @Train

Ileesẹ reluwe ilẹ wa ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọkọ oju irin kan to ko ero, tẹ alagbe kan pa lagbegbe Muslim, nilu Eko.

Lasiko to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin nilu Eko, Jerry Oche, tii se ọga agba fun ẹka to n risi ibasepọ pẹlu ara ilu, salaye pe ọkọ oju irin to n lọ lati agbegbe Ijoko si Iddo lo tẹ alagbe naa pa lẹba tesan reluwe to wa ni Mushin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa ni onibaara ti o jẹ Ọlọrun nipe naa jẹ ọkan lara awọn alagbe to maa n joko lẹba oju irin ni tesan Mushin.

Nigba to wa n kẹdun lori iku alagbe naa, Oche tun rọ awọn ara ilu lati mase tako awọn ofin to rọ mọ lilo oju irin, ki wọn si dẹkun jijoko sẹba oju ọna reluwe, boya lati se agbe ni tabi fun idi miran.

Àkọlé fídíò, Mò ń fi lẹ̀kẹ̀ ya àwọnran láti jèrè ǹkan méjì - Olaniyi Olaniyan

Bakan naa lo tun rọ awọn ontaja, awọn to n kiri ọja, awn onibaara atawọn araalu lapapọ, lati rin jinna kuro lawn opopona oju irin, ki wọn lee dina ijamba.