Reluwé Abuja: Amaechi ní èrò pọ̀ ní ojú ìrìn Abuja si Kaduna nítori ìjínigbé lójú pópó

Oríṣun àwòrán, Amaechiofficial
Ìjọba àpapọ ti pinu lati ra iyara ikero méjì míràn láti fi kún ọkọ oju irin to n ná Abuja si Kaduna, eyi ti yoo mu àdínku ba èrò àpọjú to fẹ wọ ọkọ oju irin.
Mínísítà feto ìrìnà, ọ̀gbẹ́ni Rotimi Amaechi, ló pàsẹ bẹ́ẹ̀ ni lásìkò tó ń sàbẹ̀wò si iṣẹ́ ojú irin tó ń lọ lati ilu Eko si Ibadan, ni adugbo Ologuneru ni ìlú Ibadan.
Iròyìn NAN fi yẹ ni pé, ẹsẹ̀ kò gbà àgọ ìwọ̀kọ ojú ìrìn tó n rin Abuja si Kaduna mọ, nítori iwa ìjínigbé tó ń wáye lopopona Kaduna si Abuja lójoojúmọ.
Amaechi sọ pé, ile iṣẹ́ ọkọ oju irin (NRC) yóò gbe yàrá ìkérò si méjì míràn láti Itakpe si Warri, wá si ti Kaduna-Abuja.
Ó kìlọ̀ pe, gbogbo àwọn oṣìṣẹ ti ọwọ́ pálábá ba ṣegi nínú tita tíkẹ̀ti ní owó rẹ jú iye to yẹ ko jẹ lọ, yóò fi oju wina ofin.
Amaechi ni ko ni rọrun lati lè móju to àwọn èrò to ba n ninu ọkọ ojú irin pàápàá jùlọ lásiko ti wọn ba ń rin irin ajo









