Beckham: Èdè mẹ́sàn-án ni Beckham fi gbógun ti àrùn ibà

Oríṣun àwòrán, @malariamustdie
Gbajugbaja agbabọọlu ọmọ ilẹ Gẹẹsi tẹlẹ, David Beckham tun ti gba ọna ara miran yọ sawọn eeyan agbaye, paapa awọn ololufẹ rẹ.
Ninu fidio kan to ti di tọrọ fọn kale bayii, ni a ti ri Beckham to n lewaju ipolongo tuntun lati gbogun ti aisan iba, to si sọ ede mẹsan-an gbako ọtọọtọ ninu fidio naa.
Beckham yii, lo n sọrọ ninu fidio ranpẹ naa, ni wọn lo imọ ẹrọ igbalode fun, to si n sọ ede Swahili, Kinyarwanda, Arabic, Yoruba, Faranse, Spanish, Hindi, mandarin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn ete ati oju rẹ lo n lọ soke sisalẹ bo se yẹ lasiko to n sọ awọn ede naa, sugbọn awọn ohun to n jade lo dabi ti ohun awọn eeyan ti ori ko yọ lọwọ aisan iba.
Awọn to se agbatẹru fidio naa lero pe, awọn eeyan jakejado agbaye naa yoo wo fidio yii, ti wọn yoo si fi ohun tiwọn naa si pẹlu.
Afojusun wọn nidi sise eyi ni pe, wọn yoo lo ohun awọn eeyan yii lati wa eekanna mọ awọn asaaju orilẹede agbaye lọrun, nibayi ti wọn n gbaradi lati gbe ipinnu kalẹ lori agbekalẹ apo asunwọn ẹdawo kan, eyi ti yoo maa gbogun ti aisan AIDS, ikọ ife, ati aisan iba.
Bi fidio naa se lọ ree:
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post









