Imo Airport Fire Outbreak: Iná sọ ní pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Imo

Oríṣun àwòrán, DANIEL NWACHUKWU
Lẹyin ti ijamba ina kọ lu papakọ ofurufu ipinlẹ Imo, igbokegbodo irinajo ti gberasọ pada.
Ni ọjọ aje, ọjọ kẹjọ oṣu kẹrin ni iṣẹlẹ ijamba iná yii waye ní pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Imo.
Akọroyin BBC fi aridaju han pe ina naa pọ jọjọ to bẹẹ ti wọn dari irinajo pẹlu baalu lọ si ilu Portharcourt.

Oríṣun àwòrán, DANIEL NWACHUKWU
Ipaya bẹ silẹ gẹgẹ bi ina naa ṣe bẹrẹ si ni jo wii wii ni ẹnu ọna abawọle papak ofurufu Sam Mbakwe ni ilu Owerri, ipinlẹ Imo.
Ohun to ṣokunfa ina naa ko tii hande gẹgẹ bi a ko tii gbọ latẹnu awọn alaṣẹ tọrọ kan gan.









