Dókítà yọ oyin mẹ́rin tó n gbé nínú ẹyinjú arábìnrin kán

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arabinrin ọmọ ọdun mejidinlọgbọn kan ti wọn pé ni Ms He ni àwọn oyin mẹrin sọ ẹyinju rẹ di ibugbe.
Obinrin yii jẹ ọmọ orilẹ-ede Taiwan ni eyi ti awọn oniṣegun oyinbo rii pé awọn oyin ti wọn fẹran ilaagun eniyan sọ oju rẹ di ilé.
Dokita Hong Chi Ting ti ile iwosan Fasiti Fooyin ni Taiwan ṣalaye fun BBC pẹ ẹnu ya gbogbo àwọn nile iwosan naa nigba ti awọn ri oyin mẹrin ti ikọọkan wọn to iwọn milimita mẹrin yọ loju arabinrin naa.
Awọn onimọ fidi ẹ mulẹ ni Taiwan pé igba akọkọ ni yii ti wọn yoo ri iru iṣẹlẹ yii lẹnu iṣẹ wọn.
Dokita Hong Chi Ting ni wọn ti yọ oyin naa loju arabinrin He; wọn de ti fii silẹ ki o maa lọ sile rẹ ni alaafia.
Iwadii Kansas Entomological Society fihan pé omi ẹkun ojú kun fun eroja oriṣii.
Awọn irufẹ oyin ti wọn fẹran ilaagun bayii maa n saaba ba si ara eniyan lati la ilaagun ara wọn ni.
Iwadii fihan pe wọn tun maa n fẹ la omi ẹkún ojú eniyan nitori eroja aṣaraloore to wa ninu omi ẹkun.
Bawo ni Oyin ṣe di onile ninu ẹyinju Obinrin yii:
Arabinrin Ms He ni oun n tu koriko ni bebe iboji mọlẹbi oun nigba ti oyin ko sinu ojú oun.
O ni asiko yii ni oun n kopa ninu ajọdun ọlọdọọdun 'Ṣiṣe atunṣe si iboji mọlẹbi'ti wọn n pe ni: Qing Ming Tomb-Sweeping Festival lọwọ.
Arabinrin He ni ṣaa dede ni atẹgun kan fẹ wa nibi iboji ti oun ti n tu koriko yii ni eyi ti oun fi kọkọ ro pe idọti lo ko si oun loju.
O ni lẹyin wakati diẹ ti oju oun ṣi wu sibẹ ti ojú n ta oun ni oun ṣẹṣẹ gba pé kii ṣe idọti lasan ni o ko si ẹyinju oun.
O ṣalaye fun akọroyin BBC pé nigba ti ọrọ oju yii fẹ maa gba ẹbọ lọwọ oun ni oun ba morile ile iwosan ni Guusu Taiwan.
Dokita Hong ni "nigba to fi maa de ile iwosan, ko le pa oju rẹ de mọ, mo fi ẹrọ amunkan tobi sii wo ẹyinju rẹ ni mo ba ri awọn nkan dudu to dabi ẹsẹ kokoro ninu oju rẹ".
O ni kete ti oun yọ ẹsẹ alakọkọ ni oun ri awọn kokoro oyin to ku ninu oju arabinrin naa.
Dokita naa ni oyin mẹrẹrin lo ṣi wa laaye lasiko yii.
O ni inu oun dun pe arabinrin yii ko ba iṣẹlẹ naa rin nitori pe ori koo yọ pe ko fi ọwọ gbo oju rẹ nigba ti awọn kokoro naa wa ninu ẹyinju rẹ.
Arabinrin He ni oun n wọ jingi kekere ti wọn n wọ fi bo ẹyinju (Contact lense) ni eyi ti ko jẹ ko ṣeeṣe fun oun lati fọwọ gbo ẹyinju oun ki oun to de ilé iwosan.
Eyi ni oye ṣẹṣẹ yee pe bi bẹẹ kọ ni o ṣeeṣẹ ki oju oun ti fọ lataari omi ara oyin naa ka ni oun fọwọ gbo oju ṣaaju ile iwosan ni.
Dokita Hong ni awọn oyin mẹrẹrin ṣi wa laaye, ati pé wọn ti fi awọn oyin naa ranṣe si ile iṣẹ imiran ti wọn yoo ti ṣiṣẹ iwadii to peye nipa wọn nitori pe, igba akọkọ ni yii lorilẹ-ede Taiwan ti iru nkan bayii a ṣẹlẹ.


















