Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa DCP Kayọde Ẹgbẹdokun

Kayọde Ẹgbẹtokun, ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Ẹgbedokun

Àkọlé àwòrán, Ọlọpaa to kawe jinlẹ ni Kayọde Ẹgbẹtokun

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria ti yan kọmiṣọna ọlọpaa tuntun fun ipinlẹ Eko.

Wọn gbé igbesẹ yii lẹyin ti wọn ti paṣẹ fun kọmiṣọna ọlọpaa nibẹ tẹlẹ, Edgal Imohimi, pé ko lọ gba ipo gẹgẹ bii ọga ọlọpaa tuntun fun ẹka to n n mojuto iṣẹlẹ ibugbamu ni olu ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede Naijiria to wa ni ilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbakeji Kọmiṣọna Ọlọpaa, DCP Kayọde Ẹgbẹtokun ni ọga agba ọlọpaa tuntun ti wọn yan fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko.

Ni ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan an, ọdun 1964 ni wọn bi Ẹgbẹdokun ki o to darapọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ni ọdun 1990.

line

Kini awọn ohun miran to yẹ ki o mọ nipa Ẹgbẹdokun, ọga ọlọpaa tuntun nipinlẹ Eko?

  • Ni ọdun 1999 ni wọn fi ṣe olori ikọ alaabo fun gomina ipinlẹ Eko nigba naa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.
  • O ti fi igba kan ri jẹ olori ikọ alaabo ipinlẹ Eko, Rapid Respond Squad, RRS.
  • O tun jẹ ọga agba ikọ ọlọpaa kogberegbe, Mopol 5 to wa ni ilu Benin.
  • O ti fi igba kan naa jẹ olori ẹka agbogun ti iwa ijẹkujẹ nileeṣẹ ọlọpaa olu ilu orilẹ-ede Naijiria, Abuja.
  • O ṣe akoso ẹka iṣakoso nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko.
  • O ti jẹ Ọga ọlọpaa agbegbe, (area commander) ni agbegbe Oṣogbo ni ipinlẹ Ọṣun, ati Gusau ni ipinlẹ Zamfara.
  • Bakan naa lo ti ṣiṣẹ olukọ imọ iṣiro fun igba diẹ ni ilẹkọṣẹ gbogbonṣe YABATECH ki o to darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa.
line
Àkọlé fídíò, Moses Melaye: Dino Melaye sùn ìta gbangba mọ́jú níléesẹ́ DSS

Ọlọpaa to kawe jinlẹ ni ọgbẹni Ẹgbẹtokun pẹlu iwe ẹri imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ iṣiro, (B.Sc Mathematics), iwe ẹri imọ ijinlẹ keji ni imọẹrọ, (M.Sc Ẹngineering Analysis) iwe ẹri PGD ninu imọ ọrọ aje nipa epo rọbi, Petroleum Economics ati imọ ijinlẹ akoso okoowo, MBA.

Ile ẹkọṣẹ ọlọpaa to wa ni Ikẹja nilu Eko ni Ẹgbẹdokun wa gẹgẹ bii igbakeji ọga agba nibẹ ki wọn to yan an si ipo adele Kọmiṣọna nipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Alao Akala:Èmi àti Ajimọbi kò ṣe ìlérí kankan fún ara wa
Àkọlé fídíò, Claudiah: ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi fínra fún ọpọlọpọ ọdún
Àkọlé fídíò, Ronke Oṣodi: òótọ́ ọ̀rọ̀ máa ń korò gan ni f'áwa èèyàn