Lagos Flood: Wọ́n ṣì ń wa àwọn ọmọ méjì tí àgbàrá òjò wọ́ lọ ní Ketu l'Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ibeere to n jẹ jade ni pe ṣe awọn ọmọ naa ṣi wa laaye abi wọn ti gba tibi agbara ojo yii re lọ sọrun?
Wọn ṣi n wa awọn ọmọ meji kan ti iroyin sọ pe agbara ojo gbe lọ lalẹ ọjọ Abamẹta ni agbegbe Ketu ni ipinlẹ Eko.
Ariwo "ẹ gba wa o, ko sina ni gbogbo adugbo wa o! Gbogbo agbegbe lo dudu raki raki" ni awọn ara adugbo fi bọ ẹnu ti wọn si n kigbe pe agbara ojo ti wọ ọmọ meji lọ.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni kete ti awọn gba ipe nipa iṣẹlẹ yii lawọn kan si agbami iṣẹ. Wọn ri iwadi pe nkan bii ago mẹjọ alẹ ni iṣẹlẹ naa waye ti ọmọ awọn ọmọde meji si ti ba agbara ojo ti ọwọ rẹ le ọhun lọ.
Ati ajọ LASEMA ati ileeṣẹ panapana Eko ni wọn pawọpọ fun iṣẹ naa ti ikọ adoola si kan sinu omi naa lati maa wa awọn ọmọ to sọnu.
Ohun kan ti wọn tun ri ni wipe ọna kan wa to n yọ to si lọ taara latoju gọta lọ sinuu kanaari kan, ibi yii ni wọn ni o nira lati wọ.
Ẹwẹ, ninu atẹjade ti oludari agba ajọ LASEMA, Ọmọwe Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu fọwọ si, wọn gba gbogbo araalu nimọran lati maa moju to awọn ọmọde gidi gan lawọn agbegbe ti iṣoro omiyale n da laamu.
Atẹjade naa ko sọ boya wọn ti ri wọn, boya wọn ti ku tabi wọn wa laaye ṣugbọn ohun taa gbọ ni pe wọn ko tii ri ara wọn.
Ní Zamfara, Òjò àrọ̀ọ̀dá ló fa ìjàmbá ọkọ̀ kan, tí ọ̀pọ̀ míì si fara gbọgbẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Olólùfẹ PDP 18 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ lásìkò tí wọn ń lọ pàdé gómìnà
Arinfẹsẹsi ko kan maili, ọba oke ni ko maa sọ wa.
Se ni ilu Gusau, nipinlẹ Zamfara kan gbinrin nipari osu Kẹjọ ọdun 2020 nigba ti eeyan mejidinlogun latinu ọpọ ẹbi tẹri gbasọ ninu ijamba ọkọ .
Ọjọ buruku esu gbomi mu si ni ọjọ naa lopopona Tsafe si Gusau nigba ti Tirela ati ọkọ ayọkẹlẹ mẹrin kọlu ara wọn ni deede aago mẹrin abọ irọlẹ.
Lara awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa si ni ọmọ ẹgbẹ oselu PDP mejidinlogun naa wa, ti wọn n lọ ki gomina wọn kaabọ pada waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Nàíjíríà ti pín yẹlẹyẹlẹ láyé Buhari, ìjákulẹ̀ dé! - Obasanjo gbarata
- Iyabo Ojo ṣílé, Toyin Abraham fẹ́ ṣílé iṣẹ́ f'ọmọ, àtàwọn nǹkan míràn lágbo òṣéré
- Wo fọ́tò àrà MC Oluomo, Pasuma àtàwọn òṣèré tíátà míì níbi ìṣílé Iyabo Ojo
- Wo àwọn òṣìṣẹ́ kólẹ̀-kódọ̀tí tó ń fi ẹ̀mí wọn wéwu kí Abuja leè mọ́ tónítóní
- Àwón Oníbúrẹ́dì ń gbé ìgbésẹ̀ láti fi kún owó Búrẹ̀dí ní Nàìjírià
- Wo ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta tó ti pé ọdún 48 tó ń ṣe ìdánwò WAEC, kó le di nọ́ọ́sí
Alhaji Bello Matawalle lo ti rinrin ajo lọ silu Abuja lati ọsẹ diẹ sẹyin, to si n pada bọ wa sipinlẹ Zamfara lọjọ naa.
Ọkan lara awọn eeyan tori koyọ ninu ijamba ọkọ naa, Malam Bello Bakada ni bii idan ni isẹlẹ naa waye, eyi to ba ọpọ wọn lojiji.
"Ojo n rọ lakọlakọ lọjọ naa, to si nira fun awakọ lati ri ọkankan, koda, a ko lee ri ọkọ to n bọ niwaju, lojiji ni tirela kan sadede rọ lu ọkan lara awọn mọto wa.
Eeyan mejeeje to wa ninu ọkọ naa ku loju ẹsẹ, ti mọto meji miran si tun rọ lu tirela naa, eyi to tun mu ẹmi eeyan mọkanla miran lọ."
Gomina Watawalle, to ti fẹrẹ wọ ilu Gusau lasiko naa pada sibi isẹlẹ ọhun, to si lo ọpọ wakati lati ko awọn oku lọ sinu ilu fun sinsin.

Oríṣun àwòrán, @Bellomatawalle1
Ko tan sibẹ, ọpọ awọn eeyan to forei sọta ijamba yii lo tun fara gba ọgbẹ lorisirisi.
Bakada ni "ọjọ meji ni mo fi daku, ki n to ji, ti mo si ri pe ẹsẹ mi ti da, tawọn oniruuru ọgbẹ si wa lara mi.
Ohun ti mo ranti gbẹyin ki n to ba ara mi nile iwosan ni pe mo ri tirela to rọ lu wa, ti ohun gbogbo si pada dudu."
Gómìnà Zamfara kò lágbára ní tòtọ́ọ́ lórí ọ̀rọ̀ ààbò- amòfin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abdul’aziz Yari
Amofin Oyeyemi Balogun sọ pe otitọ ni ọrọ ti gomina ipinlẹ Zamfara governor pe oun ko lagbara to to lati paṣẹ fawon soja ati awọn agbofinro mii lati dẹkun ipaniyan to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa.
Nigba ti o ba BBC Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Balogun ṣalaye wi pe fidihẹ lasan ni awọn gomina ipinlẹ lori ohun ti wọn le ṣe lori ọrọ eto aabo nipinlẹ wọn.
O ni awọn gomina dabi aja ti ko leyin lẹnu ti ko si tun lee gbo debi pe yoo bu eeyan jẹ, nitori gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto aabo pata wa labẹ aarẹ orilẹede Naijiria.
Amofin Balogun fikun ọrọ rẹ pe kọmisọnan fun ilẹ iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ le kọ eti ikun si aṣẹ ti gomina ba pa ayafi ti o ba gbasẹ lati ọdọ ọga ọlọpaa ni Naijiria.
Ọgbẹni Balogun ni ọlọpaa ipinlẹ ni ọna abayọ si iṣoro eto aabo kaakiri orilẹede Naijiria.
Ṣugbọn o sọ pe awọn gomina lorilẹede Naijiria ko ti ni iriri lati dari ọlọpaa ipinlẹ.
Amofin naa rọ awọn aṣofin ati awọn alaṣẹ ijọba lati ṣe ayẹwo iwe ofin Naijiria papaa julọ ẹka to nii ṣe pẹlu eto aabo.
Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ni oun nikan ko ni oun maa maa lo agbara lori eto aabo nitori pe gomina naa ipinle kookan naa ni agbara lati daabo bo awọn eniyan ipinlẹ rẹ.
















