Yoruba films: Gbogbo bó ṣe lọ rèé lágbo òṣéré láàrín ọ̀sẹ̀ yìí

Mercy Aigbe ati Omo rẹ

Oríṣun àwòrán, Mercy Aigbe

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Mercy Aigbe to ṣẹṣẹ ṣe agbejade fiimu tuntun kan ti fi oju ọmọ rẹ, Juwon han gẹgẹ bi ọkan lara awọn to kopa.

Igba akọkọ niyi ti Juwon yoo maa kopa ninu ere Tiata gẹgẹ bi iya rẹ ṣe fi sita loju opo Instagram rẹ.

Mercy Aigbe ni iwuri ni eyi jẹ fun oun gẹgẹ bi iya Juwon to ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi oṣere.

Mercy Aigbe ti oun funra rẹ naa kopa ninu fiimu to si tun jẹ igbakeji adari ere ni awoṣifila ni sinima naa to pe akọle rẹ ni "Kini Igbeyawo" yoo jẹ.

Lara awọn mii ti wọn tun jọ kopa ninu ere ọhun ni Yemi Blaq, Nkechi Blesssing, Bolanle Ninalowo, Peters Ijagbemi ati awọn mii.

Àkọlé fídíò, Bọlanle Ninalowo: Ọ̀rẹ́ lásán àti olóore mi ni Mercy Aigbe

Gbogbo bó ṣe lọ rèé lágbo òṣéré láàrín ọ̀sẹ̀ yìí

Nollywood

Oríṣun àwòrán, others

Bẹbẹ ṣẹlẹ lagbo oṣere laarin ọsẹ yii, bi awọn kan ṣe n ṣi ile awo dami ẹnu, lawọn mii n ṣi ileeṣẹ f'ọmọ, lawọn kan naa jẹpe Eledumare.

Ẹ jẹ ka bẹrẹ lati ọdọ oṣere to si ile tuntun laarin ọsẹ yii.

Iyabo Ojo

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Iyabo Ojo ṣi ile tuntun laarin ọsẹ yii, nibi ti ọpọlọpọ awọn ẹbi, ọrẹ ati ojugba rẹ ninu iṣẹ tiata peju si.

Ṣaaju ni ọkan lara awọn ọmọ oṣere naa, Priscilla, ti kọkọ kede lori ayelujara pe iya oun ti di onile niluu Eko, eyii to mu ki ọpọ awọn eeyan kii ku ori ire.

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabode Omo ladukeade

Awọn oṣere jankan jankan ati awọn eeyan miran bii, Alhaji Alabi Pasuma, MC Oluomo atawọn gbajumọ lawujọ lo peju si ibi ayẹyẹ iṣile naa lati ba ṣọjọyọ.

Toyin Abraham

Lẹyin ọjọ diẹ to ṣe ọjọ ibi, Toyin Abraham kede pe oun, ọkọ oun ati awọn eeyan kan yoo ṣi ileeṣẹ fun ọmọ rẹ, Ire, laipẹ.

Toyin sọ loju opo Instagram rẹ pe ileeṣẹ naa yoo da lori idilẹ ati eto ẹkọ, eyii ti wọn yoo fi sọri ọmọ naa.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ fun ifẹ wọn lori idile rẹ.

Baba Legba

Bo tilẹ jẹ pe o ti ṣe die ti o ti kopa ninu ere agbelewo, aarin oṣẹ yii ni Alhaji Yekini Omobolanle, ti ọpọ mọ si Baba Legba jade laye.

Ebun Oloyede, ti ọpọ mọ si Olaiya Igwe lo kọkọ fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba pe Baba Legba ti papoda.

Àkọlé fídíò, Mistura Oseni Akintunde: Ara múmú kìí ṣe oríṣun ìfipábánilòpọ̀, ìran àwòjù ló ń fà á

Iroyin ni Baba Legba jade laye lẹyin aisan ranpẹ ni ile rẹ to wa ni Abeokuta.

Ijebuu

Aarin ọsẹ yii kan naa ni Olatayo Amokade, ti ọpọ mi si Ijẹbu polongo loju opo Instagram rẹ pe awọn ololufẹ oun ti le miliọnu kan ati abọ lori ikanni naa.

O ni "mo dupẹ lọwọ gbogbo ẹyin milọnu kan ati abọ to n fifẹ han si mi."

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Eniuola Badmus

Eniola Badmus ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si gbogbo Bis girls naa ṣọjọ ibi laarin ọsẹ yii.

ENIOLABADMUS

Oríṣun àwòrán, ENIOLABADMUS

Oriṣiriṣi aworan ni Eniola ko soju ikanni Instagram rẹ lati fi sami si ọjọ ibi naa.

Ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo si n ki ni mẹsan an mẹwaa.

Àkọlé fídíò, Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí