Ondo Election 2020: Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ó dá àwọn lójú pé àwọn yóò jáwé olúborí

Oríṣun àwòrán, Google
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni bi awọn ṣe jawe olubori ni idibo sipo gomina nipinlẹ Edo, bẹẹ ni yoo ṣe ri fun awọn ni ipinlẹ Ondo.
Ẹgbẹ oṣelu PDP, lo fi lede bẹẹ nibi ti wọn ti n dun inu wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP jawe olubori ni ipinlẹ Edo.
PDP ni bi awọn ṣe jawe olubori naa ni ipinlẹ Edo fun awọn ni agbara lati ṣiṣẹ takuntakun, ki awọn le jawe olubori ninu idibo ti yoo waye ni ipinlẹ Ondo ni oṣu to n bọ.
Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC lo kede Gomina Godwin Obaseki ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo bori ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ naa ni Ọjọ Satide.
Nibayii, gbogbo oju lo wa lara idibo sipo Ondo ti yoo waye ni Ọjọ Kẹwa, Oṣu Kẹwa, ọdun 2020.
Gomina Oluwarotimi Akeredolu n dije dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nigba ti Eyitayo Jegede n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi naa ko gbẹyin nibi idibo sipo gomina nipinlẹ Ondo naa, ẹgbẹ oṣelu ZLP niawọn yoo ti dije dupo.
Àjọ Elétò ìdìbò INEC ti sọ̀rọ̀ lórí iná tó jó àwọn káàdì ìdìbò ní Ondo
Ajọ to n ri si eto idibo lorilẹ-ede Naijiria, INEC, ti sọ pe Ina to ṣẹyọ ni ọfiisi rẹ to wa ni ilu Akure ko ni ṣakoba fun eto idibo to n bọ ni ipinlẹ ọhun loṣu kẹwaa ọdun yii.

Oríṣun àwòrán, Olawale Abolade
Alaga ajọ naa ni ipinlẹ Ondo, Rufus Akeju ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa ina ọhun ni eyi ti wọn yoo si gbe si ojutaye bi o ṣe yẹ.
Bakan naa lo fi awọn Oludibo ni ipinlẹ Ondo lọkan balẹ pe, ijamba ina naa ko ni ṣakoba kankan fun bi eto idibo naa yoo ṣe lọ ni ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.
Iṣẹ́ jìbìtì ni INEC fi ọ́ọ́fìsì rẹ̀ tó jóná l'Ondo ṣe - Eyitayo Jegede
Àwọn olùdíje dupò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ondo ń fapájánu lórí ilé iṣẹ́ INEC to jọ́ná
Ó ṣeni laanu pe iru iṣẹlẹ yìí ṣẹlẹ nítori pe o fi han pe, awọn kan ko fẹ́ ki idije yiìí yọri si rere, àwọn èèyàn mu ero ọkan wọ́n ṣẹ ni.

Oríṣun àwòrán, oTHERS
Ó jẹ́ ibàlórúkọ jẹ́ fún ìpińlẹ̀ Ondo nítori pe ilu to ni iyi ati ogo ni.
Eyi ni ọ̀rọ̀ ọmọ ọba Dapo Adelegan tó jẹ́ oludije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC).
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Àlàyé rèé lórí bí mo ṣe fi ọsàn híhó fẹ́ ìyàwó mi"
- Wo àmì márùn-un tí o fi le mọ ẹni tó fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀
- Típà tẹ dẹ́rẹ́bà pa ní Epe
- Ọwọ́ tẹ ọkùnrin kan ní pápákọ̀ òfurufú l‘Eko tó ń kó ike ATM 2,886 lọ si Dubai
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ìjọba Kwara fẹ́ sọ orúkọ Rashidi Yẹkini di mánigbàgbé
- Ọ̀kẹ àìmọye ẹ̀rọ àyẹ̀wò káàdì olùdìbò jóná mọ́lé l' Ondo
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
Adelegan ní ètò idìbò ṣe pataki si idagbasoke ara ilu lọdun mẹrin-mẹrin, nitori naa ko yẹ ki iru nkan bayii maa ṣẹlẹ niru asiko ti a wa yìí
O yẹ ki wọn ni ore ọfẹ lati yan ẹni to ba wu wọn kii ṣe pe ki awọn oloṣelu nitori ifẹ ara wọn ma a di wọn lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Olawale Abolade
O ní kaadi ko le dede jona, awọn kan lo lọ fi ina sii.
Adelegan wa rọ ijọba apapọ lati daabo bo àwọn nkan idibo yii ju ti tẹlẹ lọ.
"Mo fẹ lọ si ile iṣẹ ajọ eleto idibo bayii fun ibanikẹdun ati lati sọ fun wọ́n pé, ki wọn tete wa ojutu si gbogbo nkan to jona lasiko iṣẹlẹ naa.
Ninu ọrọ tirẹ, oludije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP) ni ìpínlẹ̀ Ondo Eyitayo Jegede ni, oju oluwa n ri ẹni to dan nkan to ṣẹlẹ naa wò.

Oríṣun àwòrán, Olawale Abolade
Jẹgẹde ni ki lo de ti ile iṣẹ INEC ko jona saaju asiko yii. "Iṣẹ jibiti wọn lo bẹrẹ yẹ" " Nkan itiju ni" sebi Naijiria yii ti da tẹlẹ rii, "kilo de ti a le gbe ogo orilede yii"
Jegede ni ki ẹnikẹni ma sọ pé ǹkan idi kankan jona oo, " ṣe bi wọn ni ilé iṣẹ́ ni Abuja, ki wọn ya ko àwọn nkan miran wa lati Abuja fun eto idibo to n bọ.

Oríṣun àwòrán, @NewsOfNigeria
Ondo INEC: Iná ṣọ lọ́fíìsì àjọ INEC, ohun èlò fún ìdìbò Ondo jóná mọ́lé
Ọkẹ aimọye awọn ohun elo fun ayẹwo kaadi awon oludibo lo ti jona mọle lolu ileeṣẹ ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria, INEC ni ipinlẹ Ondo to wa niluu Akurẹ.
Gẹgẹbi, iroyin ṣe sọ, ni aṣalẹ Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa wa'ye.
Amugbalẹgbẹ fun alaga ajọ INEC lori eto iroyin, Rotimi Oyekanmi fi idi rẹ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
- Gbèsè Nàìjíríà ti lé ní 18 tírílíọ́ọ́nù lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Buhari- DMO
- Wo bí iṣẹ́ abẹ wákàtí mẹ́fà, tí wọ́n fi dóòlà ẹ̀mí ìjàpá tí ọkọ̀ tẹ̀, ṣe lọ
- Kò sóhun tó ń jẹ́ ‘Captivus’ nílẹ̀ Oodua, mágùn ni mágùn ńjẹ́ - Babaláwo
- Wo àwọn obìnrin abúlé kan tó dáwó ra ọkọ̀ láti máa gbé aláboyún lọ ilé ìwòsàn
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
Ọkan lara awọn kọmiṣọna agba fajọ INEC, Amofin Festus Okoye to wa ni ipinlẹ̀ Ondo lọ̀wọ bayii lori ọrọ idibo naa la gbọ pe o sa kijokijo lọ si olu ileeṣẹ ajọ INEC naa lati mọ bi ọwọ̀ja rẹ ṣe pọ to.

Oríṣun àwòrán, @NewsOfNigeria
Awọn oṣiṣẹ panapana tete de sibi iṣẹlẹ ọhun lati bu omi pa ina naa eleyii to ti bẹrẹ si ni jo inu agolo ikẹrususi kọntena ti wọn ko awọn ẹrọ ayẹwo kaadi oludibo naa si
Bi o tilẹ jẹ wipe ko si ẹni lee sọ ni pato bi ina naa ṣe bẹrẹ ati ohun to ṣokunfa rẹ, Amofin Okoye ti fi da araalu loju pe iwadii yoo waye lati tu mọ ohun to ṣokunfa ijamba ina ọhun.

Oríṣun àwòrán, @Moneycentral4
Ajọ eleto idibo Naijiria, Independent National Electoral Commission (INEC) ti kede pe eto gbogbo ti to de eto idibo lati yan gomina tuntun ti yoo waye ni ipinlẹ Ondo lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.
A ti gba àwọn òṣìṣẹ́ 15,000 làti ṣètò ìdìbò gómìnà ní ìpínlẹ Ondo lóṣù kẹwàá - INEC
INEC ni awọn ẹgbẹrun mẹẹdogun oṣiṣẹ ni yoo jẹ awọn agunbanirọ ti wọn n sinru ilu ilẹ baba wọn nipinlẹ Ondo.
Awọn ẹgbẹrun meji to ku yoo jẹ oṣiṣe awọn oṣiṣẹ ile iwe giga kaakiri Naijiria ti yoo to esi papọ, ti wọn yoo si jẹ alabojuto.
Ogbẹni Fetsus Okoye to jẹ kọmiṣọnna agba fun idanilẹkọọ lori eto idibo ati oludibo sọ eyi di mimọ nibi idanilẹkọọ ọlọjọ kan ti wọn ṣe pẹlu awọn akọroryin.
Okoye ṣalaye awọn igbesẹ ti ajọ INEC ti la kalẹ nipa eto idibo naa.
O ni aago mẹjọ abọ aarọ ni eto idibo naa yoo bẹrẹ ti yoo si pari ni aago meji abọ ọsan ọjọ naa.
- Kò sóhun tó ń jẹ́ ‘Captivus’ nílẹ̀ Oodua, mágùn ni mágùn ńjẹ́ - Babaláwo
- Wo àwọn obìnrin abúlé kan tó dáwó ra ọkọ̀ láti máa gbé aláboyún lọ ilé ìwòsàn
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Alámì ẹ̀yẹ Scrabble Paul Sodje àti ọ̀rẹ́ rẹ́ kú lásìkò tó fẹ́ lọ́ sanwó ìdóòlà ẹ̀mí àbúrò rẹ̀, tí afurasí darandaran jí gbé
















