World suicide prevention: Iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn rèé láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari ní Nàìjíríà rèé

suicide

Oríṣun àwòrán, others

Mẹwaa n ṣẹlẹ ní duniyan, ẹni to kan lo mọ o. Njẹ o ti ẹ mọ iye awọn ọmọ Naijiria to ti gbẹmi ara wọn nitori bi ilu ti ri ni nkan bi ọdun mẹrin ṣẹyin?

Bi orilẹ-ede Naijiria ti darapọ mọ gbogbo agbaye lati ṣe ayajọ didena gbigba ẹmi ara ẹni, akọsilẹ ti fihan pe ọta le lugba eeyan o le mẹrin ni wọn ti ṣekupa ara wọn lorlẹede yìí lọdun mẹrin ṣẹyin.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Nigba ti akori ti ọdun yìí jẹ́ ṣiṣiṣẹ pọ lati dena iwa pipa ara ẹni, eeyan 264 gbẹmi ara wọn laarin oṣu kinni ọdun 2017 sí oṣu kẹjọ ọdun 2020 yii.

Ipinlẹ Eko lo wa loke tente, eeyan mẹtalelogun lo gbẹmi ara wọn lọdun mẹrin ṣẹyin nibẹ.

Akọsilẹ fihan pe eleyii yatọ si awọn eeyan mii to pa ara wọn ṣugbọn ti awọn akọroyin ko gbe sita.

Bẹẹ si ni iwa gbigba ẹmi ara ẹni lodi si ofin orile-ede Naijiria, koda ẹwọn ọdun kan ni ẹnikẹni to ba gbiyanju lati pa ara rẹ yoo fi gbára.

Àkọlé fídíò, Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

Ipo kẹwaa ni Naijiria wa nilẹ Afrika ninu awọn orilẹ-ede ti iwa ipara ẹni tí wọ pọ julọ.

Akọsilẹ fihan pe ogunlọgọ awọn eeyan yii lo mu kẹmika "sniper" rọrun nigba t'awọn miiran pokun so.

Àkọlé fídíò, Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Iwadii tiẹ tun fihan pe niṣe lawọn mii dana sun ara wọn ti wọn sì gba ibẹ dero ọrun.

Dokita Maymunah Yusuf Kadiri to jẹ onimọ nipa aarun ọpọlọ sọ pe ibanujẹ ọkan, ijakulẹ, airiṣẹṣe, ọti mimu ati oogun oloro wa lara awọn idi to n mu ọpọ gba ẹmi ara wọn.