Rita Amenze Italy murder: Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ lórí ikú ọmọ Naijiria ní Italy

Rita Amenze

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Rita Amenze

Ijọba apapọ ti bu ẹnu atẹ lu bi okunrin kan to jẹ ọmọ orilẹ-ede Italy ṣe pa iyawo rẹ to jẹ ọmọ Naijiria.

Ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria loke okun ti pe fun iwadii ẹkunrẹrẹ lori ohun to ṣokunfa iku ẹni ọdun mọkanlọgbọn naa.

Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi lede, o ni iṣẹlẹ ọhun waye lẹyin ti obinrin naa ja iwe ikọsilẹ fun ọkọ rẹ ọhun.

Iroyin ni ọwọ ti tẹ afurasi naa ti orukọ rẹ jẹ Pierangelo Pellizzar.

Ẹwẹ, Aarẹ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria lorilẹ-ede Italy, NUNAI, Rowland Ndukuba naa ti bu ẹnu atẹ lu iṣekupa naa.

Rita Amenze

Oríṣun àwòrán, others

Bẹẹ naa ni aṣoju orilẹ-ede Naijiria si Italy, Mfawa Omini Abam ti sọ pe ọọfisi oun yoo ri daju pe awọn ṣe iwadii to peye lori iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Bawo ni iku obinrin naa ṣe waye?

Iroyin ni Rita ti kọkọ jawe mi o ṣe mọ fun ọkọ rẹ naa, eyii to bi okunrin naa ninu, to fi gbẹmi rẹ.

Ilẹ Italy ni okunrin naa, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgọta ti yinbọn pa aya rẹ, Amenze Rita, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, okunrin naa dena de aya rẹ ọhun ni nnkan bii aago meje abọ aarọ, nibi to ti yinbọn lu nigba mẹta ọtọtọ.

Ọdun 2018 tọkọ-taya naa ṣe igbeyawo lẹyin ti Rita tẹkọ leti lọ si Italy lati Libya.