SCOAN leadership tussle: Ìyàwó Wòlíì TB Joshua di olórí ìjọ Synagogue

Oríṣun àwòrán, Tb joshua
Ijọ Synagogue, SCOAN ti yan iyawo oloogbe Wolii TB Joshua, Evelyn Joshua gẹgẹ bii adari tuntun ijọ naa bayii.
Ijọ naa ṣalaye ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ pe gbogbo eto ijọ naa yoo wa labẹ itọni Ọlọrun ati idari arabinrin Evelyn Joshua bayii.
- Ẹ dákun ẹ ran Iyabo Oko lọ́wọ́, ìyá ti ń ṣàárẹ̀ láti ọdún márùn ún sẹ́yìn, o ti kọjá agbára wa- Foluke Daramola Salako
- Ṣọ́ọ̀ṣì wó pa èèyàn méjì ní Taraba, àwọn míràn farapa
- Wo iye kọ́ńdọ́mù táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ń ṣara rindin lọ́dún
- Wo ìdí tí àwọn obìnrin kan fi n yọ ilé ọmọ wọn kúrò
- Àlàyé ohun tọ́rọ̀ adarí ń dá sílẹ̀ ní ìjọ Synagogue lẹ́yìn ikú TB Joshua rèé
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, akoko ti a yan lo to, wọn si rọ gbogbo awọn ọmọ ijọ naa lati maa fi adura tii lẹyin fun ogo Ọlọrun lati maa tii lẹyin.
Ṣaaju asiko yii ni oniruru iroyin ti n kaakiri nipa edeaiyede lori tani yoo ṣe olori ijọ naa lẹyin ti oludasilẹ ijọ ọhun, TB Joshua jade laye loṣu karun ọdun 2021.
Edeaiyede naa lo faa ti wọn fi le awọn ọmọlẹyin Wolii TB Joshua kan kuro ni gbagede ijọ naa laipẹ yii.
Wolii TB Joshua ku ni oṣu kẹfa ọdun 2021
Ileesẹ iransẹ TB Joshua kede pe oludasilẹ ijọ naa ati agba wolii lorilẹede Naijiria, Temitope Balogun Joshua ti dagbere faye loju opo Facebook rẹ, lọjọ Satide, ọjọ karun osu Kẹfa ọdun 2021.

Oríṣun àwòrán, AFP
Wolii Joshua, to dele aye ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1963, lo lo ọdun mejidinlọgọta loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.
Ikede naa fidi rẹ mulẹ pe Ọlọrun kii se ohunkohun lai fi iran rẹ han awọn wolii rẹ saaju, to si tọkasi iwe mimọ Amosi, ori kẹta ẹsẹ keje.
Gẹgẹ bi ikede ijọ naa ti wi, Wolii Joshua sọrọ lọjọ Satide lasiko ipade to se pẹlu awọn alabasisẹpọ rẹ fun ileesẹ mohunmaworan ijọ rẹ, Emmanuel TV, to si dabi ẹnipe o n sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ.
- Wo nkan márùn-ún tí o kò mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàrin tọkọ-taya
- Aàrẹ Joe Biden pè fún alàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ lẹ́yìn ogún ọdún tí ìkọlù 9/11 wáyé ní America
- Wo àwọn Fasiti Nàìjíríà tó gbégbá orókè lágbàyé
- Odunlade Adekola yarí lórí ìròyìn tó ní ó n bá àwọn obìnrin sùn kó tó fi wọ́n sínú fíímù rẹ̀
- Ọmọ Naijiria tó ń ṣe Yahoo rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ̀rin he l'Amẹrika
- Pásítọ̀ Enoch Adeboye ṣàlàyé ìdí tó fi jọ́sìn ní C&S Wòlíì Esther Ajayi















