Yahoo boys in America: Ọmọ Naijiria tó ń ṣe Yahoo l'Amẹrika rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ̀rin he

Oríṣun àwòrán, succo
Ile ẹjọ kan nilẹ Amẹrika ti ran ọmọ Naijiria kan, Afeez Adebara lẹwọn ọdun mẹrin.
Adebara ri ẹwọn naa hẹ lẹyin ti wọn fẹsun kan pe oun lo n dari ẹgbẹ awọn onijibi ori ayelujara kan, ti ẹgbẹ naa wọn si ti gba ọpọlọpọ ọkẹ aimoye owo lọwọ awọn eeyan.
Lara awọn ti wọn sọ pe ẹgbẹ Adebara ti lu ni jibiti ni awọn obinrin ti wọn n wa ọkọ lori ayelujara atawọn arugbo kaakiri ilẹ Amẹrika, ti iye owo ti wọn ti gba lọwọ awọn eeyan ọhun ko si din ni miliọnu meji abọ dọla.
- Aàrẹ Joe Biden pè fún alàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ lẹ́yìn ogún ọdún tí ìkọlù 9/11 wáyé ní America
- Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Odunlade Adekola nídìí iṣẹ́ tíàtà sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn pé ó ń bá àwọn lòpọ̀
- Ìwádìí ti tú àṣírí àwọn tó yìnbọn sí olùwọ́de EndSARS ní Tollgate l'Eko
- "Kò sí ìdáríjí fún àwọn jàndùkú mọ́ báyìí, a óò bẹ̀rẹ̀ sí ń ran wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Eledumare"
- Arákùnrin ẹni ọdún 28 kan tí bá omiyalé lọ ní Ibadan
- Ọ̀bẹ ti bá ọ̀gá DPO tó sọ ìbọn ọlọ́pàá nu lẹ́yìn tó gbé obìnrin sùn sí ọ́fíìsì rẹ̀ nídí
- Àwa ọmọ ìlú Igboho kò gbàbọ̀dè fún Sheikh Gumi o, gbọin-gbọin ni à wà lẹ́yìn Sunday Igboho
Ileeṣẹ to n ri si eto idajọ nilẹ Amẹrika sọ pe Adebara jẹwọ pe lootọ ni oun ṣẹ si ẹsun ti wọn fi kan oun.
Awọn iwe lati ile ẹjọ naa fi han pe ọdaran naọhun gba owo lọwọ awọn eeyan lọna ẹburu laarin ọdun 2017 si oṣu Kọkanla ọdun 2019.
Iwe ẹjọ ọhun tun ṣafihan pe ọdanra naa atawọn to ko sọdi maa n lo oniruru ayederu orukọ ati iwe irinna lati fi bo aṣiri iṣẹ ibi ti wọn n ṣe.
Wọn tun sọ pe Adebara maa n fi owo to ba ti pa nidii iṣẹ naa ranṣẹ si Naijiria, nigba miran ẹwẹ yoo fi owo ọhun ra awọn ọkọ bọgini ti yoo ko ranṣẹ sile.
Awọn iwe ẹjọ na ni "Adebara maa n forukọ silẹ lori ikanni awọn to n wa ọkọ ati aya lati fẹ awọn obinrin, ti yo si maa gba owo gọbọi lọwọ awọn ololufẹ rẹ ọhun labẹ ayederu orukọ."
Ọọfisi ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ FBI to wa niluu Oklahoma lo ṣe iwadii naa pẹlu awọn oṣiṣẹ ọọfisi ọhun to wa ni San Francisco, Los Angeles ati New York ki ọwọ to tẹ Adebara atawọn ọmọlẹyin rẹ
- .Àwọn ajínigbé ti tú àwọn òṣìṣẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo sílẹ
- Wo ìdí tí ìwọ́de Yorùbá Nation kò fi ní wáyé mọ́ lónìí nílùú Sunday Igboho
- Nǹkan yan! Ìrẹsì, Spaghetti àti sìgá làwọn agbébọn ń béèrè fún ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bá jí gbé báyìí
- Àlàyé ohun tọ́rọ̀ adarí ń dá sílẹ̀ ní ìjọ Synagogue lẹ́yìn ikú TB Joshua rèé
- Ọkùnrin ẹlẹ́wọ̀n kan wọ gàù lẹ́yìn tó gé kórópọ̀n ẹlẹ́wọn míràn













