Bandits in Northwest Nigeria: Ìrẹsì, Spaghetti àti sìgá làwọn agbébọn tún ń béèrè fún ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bá jí gbé báyìí

awọn agbebọn to n ṣọṣẹ lagbegbe oke ọya Naijiria

Oríṣun àwòrán, other

Igbesẹ awọn ijọba ipinlẹ kan lapa iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria ti n ni ipa lara awọn agbebọn to n ṣọṣẹ lagbegbe naa bayii, gẹgẹ bi iroyin ṣe n sọ ọ.

Ko din ni awọn gomina mẹrin bayii ti wọn ti ti awọn ọja pa ni ipinlẹ wọn lati wa ọwọ awọn agbebọn naa bọlẹ ni agbegbe wọn.

Ko pẹ pupọ lẹyin igbesẹ titi awọn ọja ẹsẹkuku ni ipinlẹ Sokoto lawọn agbebọn ba bẹrẹ si ni beere fun ounjẹ gẹgẹ bi nnkan itusilẹ awọn eeyan ti wọn ba ji gbe.

Olugbe ilu kan ni Sabo Birni to ṣalaye fun awọn akọroyin sọ pe awọn agbebọn naa tu ọkan lara awọn ọmọ alabagbve oun ti wọn ji gbe silẹ lẹyin ti wọn fun wọn ni ounjẹ.

"Wọn ji ọmọbinrin arakunrin kan gbe ni ileto wa, nigba ti a ko si ri owo ti wọn beere fun ko jọ, wọn ni pe ki a lọ muiwọn abọ irẹsi mẹwaa wa ki wọn to lee tu ọmọbinrin naa silẹ, wọn si mu adehun naa ṣẹ"

Eeyan kan pẹlu tun ṣalaye fun akọroyin iwe iroyin Daily Trust ni ilu Sokoto lori bi awọn agbebọn ṣe beere fun ounjẹ ati ohun mimu ki wọn to le tu dẹrẹba wọn ti wọn ji gbe silẹ.

Àkọlé fídíò, ''N15m làwọn Fulani ajínigbé kọ́kọ́ bèèrè kí wọ́n tó gba N2.5m ọ́wọ́ wa l'Abuja''

O ni milisnu marundinlogun ni wọn kskọ beere fun ki wọn to gba ki awọn san ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira N600,000 lọwọ ọga arakunrin naa. Wọn wa ni ki ọga rẹ atawọn mọlẹbi rẹ o fi owo naa ra ọpọlọpọ apo irẹsi, apoti ohun mimu, apo ohun jijẹ Spaghetti, ati siga ki wọn si ko ṣenji owo to ba ku dani wa fun awọn.

O ni ọga arakunrin dẹrẹba naa atawọn mọlẹbi rẹ ṣi n wa owo naa bayii.