Yoruba Nation rally: ''Ìwọ́de Yorùbá Nation kò ní wáyé mọ́ nílùú Igboho torí a kò fẹ́ wàhálà''

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1
Iwọde lati pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba to ye ko waye nilu Igboho tii ṣe ilu Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si "Sunday Igboho" l'ọjọ Abamẹta ti fi ori sanpọn.
Ohun ti o ṣokunfa idiwọ fun iwọde naa ni alaga ijọba ibilẹ Orelope, Honọrebu Akeem Adepọju fi idi rẹ mulẹ lasiko to n ba akọrọyin wa sọrọ.
Adepọju ni, "awọn eeyan to kede iwọde naa ko fi ọrọ to awọn agbofinro ati awọn eeyan to n ṣe akoso ilu Igboho leti, bẹẹ sini ko si ami idaniloju wi pe awọn olubi ẹda ko ni ja iwọde naa gba lati ṣe aburu".
- Ìwọ́de Yorùbá Nation bẹ̀rẹ̀ padà nílùú Sunday Igboho lọ́jọ́ Sátidé
- Kílódé tí Sheikh Gumi fi ṣe àbẹ̀wò sí Igboho nínú gbogbo ìlú tó wà nílẹ̀ Yorùbá?
- Darandaran tó bá rúfín dída ẹran nígboro l'Ondo rugi oyin- Akeredolu yarí
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko buwọ́lu òfin máfi ẹranjẹko láàrín ìlú àti VAT
- Ìjì tó hú igi ńlá ní ìtẹ́ òkú l'Eko ba ibojì òkú 50 jẹ́, àwọn ẹbí sáré lọ w'òkú wọn
- Wo iye mílíọ̀nù tí Miyetti Allah yóò máa ta màálù kan tí ìpínlẹ̀ Eko bá fòfin de ìdẹranjẹko ní gbangba
- Àwọn jàndùkú agbébọn jí òṣìṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo mẹ́ta lọ
Alaga ijọba ibilẹ naa fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lo lẹtọ lati ṣe iwọde ati ifẹhonuhan, ṣugbọn o yẹ ki awọn agbofinro ati awọn alakoso ilu mọ si gbogbo nnkan ti wọn ba fẹ ṣe fun amọjuto to peye.
Lara awọn ọdọ ilu Igboho to n gbero lati darapọ mọ iwọde naa ṣe alaye fun akọroyin wa pe ninu ipade pajawiri kan ti awọn ṣe lalẹ ọjọ Ẹti ni wọn ti fi ohun ṣọkan wi pe iwọde naa ko ni waye.
Irẹdi pataki ti wọn fi gbe igbesẹ naa sini lati dena wahala to ṣeeṣe ko ṣu yọ ninu iru iwọde bẹẹ.
L'Ọjọbọ ni agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Ọlayọmi Koiko kede rẹ lori itakun ikansiraẹni Facebook wi pe iwọde alagbara kan yoo waye nilu Igboho nitori pe "iṣẹ Oloye Sunday Igboho gbudọ tẹsiwaju", ṣugbọn ẹni to jọ agbẹnusọ fun Ilana Oodua(ẹgbẹ kan gboogi to n le iwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Naijiria), Maxxwell Adeleye ṣe alaye pe gbogbo nnkan ti yoo mu itẹsiwaju de ba idasilẹ orilẹede Yoruba ni awọn fi ọwọ si, botilẹ jẹ wi pe awọn ko gbọ ohunkohun nipa iwọde to fẹ waye nilu Igboho l'ọjọ Abamẹta.
Adelẹye fi kun ọrọ rẹ pe Ọlayọmi Koiki lo kede iwọde naa, kii ṣe Ilana Oodua. O ni ṣugbọn eleyii ko tumọ si wi pe awọn tako igbesẹ naa.
Koiki ko tii fi ikede mii lede boya iwọde naa yoo waye tabi bẹẹ kọ, ni asiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yii.












