Anti-grazing bill: Òpin ti dé bá fífi ẹranjẹko lá̀arín ìlú – Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko

sanwo olu

Oríṣun àwòrán, @Sanwoolu

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti buwọlu ofin to ni ṣe pẹlu ọrọ owo ori tuntun fun ọja rira, VAT.

Olori ile naa, Mudashiru Obasa si ti dari akọwe ile, Lekan Onafeko lati fi ẹda iwe ofin VAT naa sọwọ si Gomina Babajide Sanwo-Olu fun ontẹ.

Ile igbimọ aṣofin ọhun tun buwọlu ofin to tako fifi ẹran jẹko laarin ilu nipinlẹ Eko.

Awọn ofin mejeji naa gba ontẹ lasiko ti awọn aṣofin ile ofọwọ si nibi ijoko wọn lẹyin ti wọn ti ka fun igba kẹta.

Ni kete ti wọn buwọlu ofin naa tan, Olori ile ọhun kan sara si awọn ọmọ ile fun akitiyan wọn lati ri pe ipinlẹ Eko ko rẹyin laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

O ni "Mo dupẹ lọwọ gbogbo yin fun igbẹsẹ ilọsiwaju ti ẹ gbe yii."

Ojọru ni awọn ọmọ ile naa ṣe ipade ita gbangba lori aba ofin ọhun, ti awọn ti ọrọ kan si sọ ni gbangba pe ohun to dara ni ofin tuntun naa ati pe yoo mu idagbasoke ba ipinlẹ Eko.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn ipinlẹ ni iha iwọ oorun Naijiria yoo buwọlu ofin to tako fifi ẹran jẹko laarin ilu.

Lọsẹ to kọja ni Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo buwọlu ni ipinlẹ re, to si sọ pe oun yoo ri daju pe ofin naa di ẹsẹ mulẹ.

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn darandaran ni Naijiria, Miyetti Allah, ti kede pe miliọnu meji naira ni awọn yoo maa ta ẹran maalu l'Eko ti ijọba ipinlẹ naa ba le buwọlu ofin ọhun.

VAT: Gómìnà Wike àti Sanwo-Olu lèwájú àwọn Ìpínlẹ̀ tó fẹ́ na tán bí owó pẹlú ìjọba àpapọ̀ lórí owó orí

Fakinfa lori gbigba owo ori ọja Value Added Tax,VAT, laarin ijọba apapọ ati awọn ipinlẹ kan ni Naijiria ko jọ pe yoo yanju laipẹ yi.

Eyi ko si sẹyin bi awọn ipinlẹ kọọkan bi ipinlẹ Eko ati Rivers ti ṣe fariga pe awọn yoo maa yọ owo lori eyikeyi ọja ti owo ori ba wa lori rẹ lai ko fun ijọba apapọ.

Nibi taa ti n sọ awọn to fẹ gba owo yi, lapa kan lawọn ipinlẹ mii bi Ondo ati Kwara ko ti mọ boya kawọn darapọ mọ awọn to fẹ gba owo tabi ki wọn jẹ ki nkan wa bo ti ṣe wa tẹlẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn agbẹnusọ Gomina ni ipinlẹ mejeeji yi, wọn ni ''A ko ti jiroro nipa rẹ. Ni kete ti ijọba ba fi to wa leti a o maa jẹ ki ẹ gbọ.''

Lootọ ni owo yi yoo ṣe anfaani fawọn to ba ri gba lati fi ṣeto idagbasoke ilu wn, ṣugbọn wọn ko yi ti fesi nipa rẹ.

Aworan Gomina ipinlẹ Rivers

Oríṣun àwòrán, Facebook/GovernorNyesomEzenwoWikeCON

Amọ bayi ti ijọba apapọ fariga pe awọn lawọn lẹtọ lati gba owo yi, ki wa ni ibi ti ọrọ yoo doju kọ?

Ki gaan ni owo ori ọja VAT ti wọn n ja si yi?

VAT jẹ owo ori ti ijọba n gba lori awọn ọja kan yala labẹ ijọba ibilẹ, ipinlẹ tabi ijọba apapọ Naijiria.

Awọn ipinlẹ to foju si owo yi ni awọn naa f maa ghba ida meje le ninu ida ọgọrun gẹgẹ bi owo ori lori awọn ọja.

Àkọlé fídíò, VAT: Kò sí àǹfàní kankan tí ìjọba ti ṣe fún mi sẹ́yìn

Ijọba apapọ lo n gbaowo yi tẹlẹ nipasẹ ajọ to n ṣeto owo ori ni Naijiria,FIRS lori karakata ọja, idokowo ati awọn nkan mii.

Amọ bayi awọn ipinlẹ bi Rivers Eko ati awọn ipinlẹ meji mii fẹ maa gba owo yi si akoto ara wọn dipo ti ijọba apapọ.

Akwa Ibom ati Adamawa lawọn meji to kun wọn.

Awijare awọn ijọba ipinlẹ yi ni pe gbigba owo yi fun ijọba apapọ tapa si ominira wọn ati pe o mu kawọn maa woju ijọba apapọ ni gbogbo igba ki wọn to na owo.

Baa ṣe n sọrọ yi, ijọba ipinlẹ Eko ti n tẹsiwaju lori abadofin ti yoo mu ki gbigba owo yi fẹsẹ mulẹ labẹ ofin.

Ijọba Ekiti Osun, Benue Bayelsa ati Gombe lawọn nilo asiko diẹ lati jiroro lori ọrọ yi.

Ẹwẹ, ile ẹjọ giga apapọ ni PortHarcourt ti gbe idajọ kalẹ pe ijọba ipinlẹ Rivers lẹtọ lati gba owo yi.

Idiwọ si gbigba owo yi wa lati ọdọ FIRS to gbe wọn lọ sile ẹjọ lori ọrọ owo yi ni gbigba.

Aworan owo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àjọ FIRS le pàdánù N2.4tn sọ́wọ́ àwọn ìjọba ìpínlẹẹ̀ Naijiria

Ileeṣẹ to n gba owo ori fun ijọba apapọ, Federal Inland Revenue Service, FIRS, lo ṣe e ṣe ko padanu owo to le ni triliọnu meji Nara (N2.4tn) sọwọ awọn ijọba ipinlẹ lọdun 2022.

Eyi yoo ri bẹẹ, ti ajọ FIRS ba fi padanu ẹjọ kotẹmilọrun to pe tako idajọ ile ẹjọ giga kan to jẹ ti ijọba apapọ.

Idajọ naa fi ofin de e pe ko gbọdọ ma a gba owo ori ọja ati owo ori eeyan.

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì

Triliọnu N2.4 ọhun ni afojusun ajọ naa pe oun yoo ri gba, ti aṣẹ gbigba owo ori ọja lọwọ awọn onibaara, ko ba fi bọ mọ lọwọ.

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ni ile ẹjọ naa to wa nilu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers dajọ pe, awọn ijọba ipinlẹ nikan lo ni aṣẹ lati ma a gba owo ori ọja, VAT, ati owo ori owo oṣu awọn oṣiṣẹ.

Amọ, ajọ FIRS pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ naa.

Awọn ijọba ipinlẹ bi i Eko ati Rivers si sọ pe awọn ti sẹtan lati bẹrẹ si ni i gba owo ori naa, ni ibamu pẹlu idajọ ile ẹjọ.

Ṣugbọn iroyin sọ pe, awọn ijọba ipinlẹ naa ni Ariwa Naijiria sọ pe o tẹ awọn lọrun ki ijọba apapọ ma a gba owo ori VAT.

Ṣaaju idajọ naa, ajọ FIRS lo ma n ba awọn ijọba ipinlẹ, ati ilu Abuja gba owo ori naa.

Wọn si ma n pin owo naa laarin ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ, ati awọn ijọba ibilẹ to wa ni orilẹ-ede Naijiria.

Ijọba apapọ ma n gba ìdá mẹẹdogun, awọn ijọba ipinlẹ ma a n gba ìdá aadọta, ti awọn ijọba ibilẹ si ma n gba ìdá marundinlogoji.

Owo ori ọja 'VAT' ni owo ti wọn ma n fi le awọn nkan ti araalu n ra nile itaja, tabi fun awọn agbaṣẹṣe. Owo ori naa ko yọ awọn ọja to n wọle lati ilẹ okeere silẹ.

Ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2021, si ni owo ori naa kuro ni ìdá marun-un to wa tẹlẹ, bọ si ìdá meje ataabọ.