Sunday Igboho: Mo ti gbà fún Ọlọ́run níbí, Ọlọrun mọ̀ sí bí mo ṣe wà lẹ́wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho/Instagram
Gbajugbaja ajafẹtọẹni fun ilẹ Yoruba nni, Sunday Igboho, ti fi ọwọ gbaya pe bi oun se wa lọgba ẹwọn ni Cotonou ko nitumọ si oun nitori o ti wa ni akọsilẹ pe oun yoo se ni.
Sunday Igboho fi ọwọ idaniloju yii sọya ninu fọnran ohun rẹ kan to gba ori ayelujara kan nilu Cotonou eyi to tẹ BBC Yoruba lọwọ.
Igboho ni gbogbo ọrọ oogun ti oun ni, fiimu lasan ni amọ irin ti oun yoo rin nile aye, titi ti oun yoo fi jade laye, o ti wa lara oun ati Ọlọrun to da oun.
- ''Ẹ ó ríjà Ọba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho''
- Kìí ṣe tuntun pẹ ìjọba Buhari tí mú Sunday Igboho, àmọ́ ọ̀nà àbáyọ sí ìtúsílẹ̀ rẹ̀ rèé - Agbẹnusọ Sunday Igboho
- Kí ló dé tí DSS kó bàńtẹ́ òògùn, ba ilé Sunday Igboho jẹ́ lái fara pa?
- Ó lé yọrí sí ogun, tí ìjọba Naijiria bá fi ìyà jẹ Sunday Igboho bí ọ̀daràn - Gani Adams
- Oríire ló jẹ́ fún Sunday Igboho bí ọwọ́ òfin kò ṣe bàá ní Nàìjíríà - Femi Falana
"Ti mo ba joko nigba miran, ti mo ba ranti ọrọ Alfa Muideen Bello, ara mi yoo balẹ ni. Lọjọ ti baba n ba mi sile, ti awọn sẹnatọ, gomina atawọn eeyan nla nla miran joko.
Alfa Muideen wa beere pe agbara ti Igboho n lo nibo lo wa, amọ gbogbo wọn n woju ara wọn, o wa ni ara mi ni Ọlọrun fi si.
O ni mo le dọbalẹ fun ọmọ ti wọn sẹsẹ bi amọ ibi ti Ọlọrun fi nnkan naa pamọ si mi lara, wọn ko le ri."
Mo ti gba fun Ọlọrun nibi ti mo wa yii:
Bakan naa ni Sunday Igboho sọ siwaju si pe oun ti gba fun Ọlọrun nibi ti oun wa yii, ti oun ko si bẹru ohunkohun mọ.
"Lẹyin Ọlọrun to ni mi, n ko bẹru ohun yowu mọ, gbogbo ohun to ba yẹ ki wọn da lara, ki wọn da.
Bi wọn ba gbe mi de iwaju adajọ yẹn, maa sọ fun pe n ko bẹru rẹ amọ mo bẹru Ọlọrun to ni mi ni, gbogbo ara ti wọn ba fẹ fi mi da, ki wọn fi mi da.
Bi wọn ba fẹ gbe mi lọ si Naijiria, ki wọn maa gbe mi lọ sibẹ, Naijria ti wọn n gbe mi lọ, ayafi ti ko ba si Ọlọrun nibẹ lo ku.
Ti Ọlọrun ba ti n bẹ ni Naijiria, ki wọn gbe mi lọ sibẹ, ko si nnkan ti wọn yoo se, sebi Kanu wa nibẹ, ija ti mo n ja ni Kanu n ja.
Gbogbo iyẹn a fi n dẹru ba ara wa ni, ti wọn ba fẹ mi lọ si Naijiria, hùn hun hún ayafi ti ko ba si Ọlọrun ni Naijiria lo ku.
Bi lọrun ba ti wa ni Naijiria, ki wọn maa gbe mi niso nibẹ, ko si ohun ti yoo sẹlẹ́."
Emi kii se ọkunrin yẹpẹrẹ, ibi to ka mi mọ ni:
Ajafẹtọ ẹni naa ni oun fi Ọlọrun bura, ọkunrin miliọnu kan ni oun, oun kii si bẹru ohunkohun amọ ibi to ka oun mọ ni.
O ni oun kii se eeyan lasan alailagbara amọ ọkunrin ni oun ti ko ba si ọkunrin nile mọ, to si se fi isẹ ogun ran.
Bakan naa lo ni oun ti yari mọ wọn lọwọ ni ọgba ẹwọn Cotonou ri pe ki wọn paarọ yara ti oun wa amọ nigba ti wọn faake kọri ni oun yari fun wọn.
Igboho ni oun kii se ọmọ kekere rara nitori ọdun yii ni oun maa pe ẹni aadọta ọdun, oun kan le ni ara kekere ni.
"Ni ọjọ ti mo change rẹ mọ wọn lọwọ nibi pe ninu ki wọn pa mi loni tabi ki wọn paarọ cell ti mo wa, wn yoo se ọkan.
Ninu kẹ yin gbogbo ibọn yin sibi tabi kẹ mu mi kuro nibi tẹ de mi mọ yii, ẹ gbọdọ se ọkan loni, wọn change rẹ tori gbogbo ohun ti mọ sọ, wọn mọ pe n ko fi bawọn sere."
Sunday Igboho ni oun n se bii dindinrin, mugun, ọdẹ fun eeyan amọ ti oun ba pada change rẹ, agbara wọn ko le ka oun mọ.
O ti wa ninu akọsilẹ pe maa se ẹwọn ni:



















