Sunday Igboho: Ó lé yọrí sí ogun, tí ìjọba Naijiria bá fi ìyà jẹ Sunday Igboho bí ọ̀daràn

GANI ADAMS AND SUNDAY IGBOHO

Oríṣun àwòrán, GANI ADAMS AND SUNDAY IGBOHO

Aarẹ ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti sọ pe igbiyanju ijọba apapọ Naijiria lati sọ igbesẹ Sunday Igboho di iwa ọdaran, ko ba ilana ijọba awaarawa mu.

Gani Adams sọ ọrọ naa ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki fun lori eto iroyin, Kehinde Aderemi fi sita lorukọ rẹ.

Awn iwe iroyin abẹle jabọ pe Adams ni ibanujẹ lo jẹ fun oun pe ọwọ tẹ Igboho.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni erongba ijọba lati ma a kọju ija si awọn ajijagbara ko bojumu, to si le sọ ijọba di ọta araalu.

"Nkan to ṣẹlẹ si Igboho n tu aṣiri diẹdiẹ pe ijọba fẹ ẹ ma a fi iya jẹ awọn ajijagbara, eyi to si le sọ ijọba di ijọba aninilara, paapaa lati ọwọ ijọba to de ipo pẹlu ileri ireti to dara ati atilẹyin awọn eniyan Iwọ-Oorun Gusu Naijiria."

Bakan naa lo ni ki ijọba fi ọwọ suuru mu ọrọ Sunday Igboho, "nitori pe fifi iya jẹ ẹ, le yọri si ogun".

"Aṣisẹ nla ni yoo jẹ fun ijọba apapọ, to ba fi le fi iya jẹ awọn ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation bi ọdaran tabi ọta.

"Igboho ni ẹtọ si ominira. Ko si si nkan to buru ninu ko wa aabo lọ si Benin Republic, tabi ilẹ okeere to ba ri i pe ko si aabo fun oun ni Naijiria."

Ọjọ Aje ni iroyin sọ pe awn ọlọpaa lorilẹ-ede Benin mu Sunday Igboho ati iyawo rẹ, Ropo, ni papakọ ọkọ ofurufu, lasiko ti wọn fẹ wọ baalu lọ si orilẹ-ede Germany.