Yoruba Nation: Ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua gbé ìwé ìforúkọsílẹ̀ àti ìlànà àátọ̀ jáde fáwọn ajìjàgbara

Awọn ajijagbara Yoruba Nation

Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua (IOY) to n se agbatẹru idasilẹ Yoruba Nation ti gbe atẹ kan kalẹ tawọn eeyan to ba darapọ mọ ijijagbara tabi lewaju rẹ, yoo ti maa fi orukọ silẹ.

Iwe oloju ewe mẹtadinlogoji naa, lo se akọsilẹ awọn ohun ti awọn ajijagbara ọhun gbọdọ se ati awọn eyi ti wọn ko gbọdọ se, pẹlu idi ti iwa ijijagbara naa fi n waye.

Iwe iforukọ silẹ naa ni asaaju ẹgbẹ IOY, Alagba Banji Akitoye fọwọsi, to si tun se alaye nipa awọn igbesẹ ti wọn gbọdọ gbe, ti iwọde ba n waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni iwe yii tun salaye idi ti ifọwọsowọpọ se gbọdọ wa laarin awọn ajijagbara fun Yoruba Nation atawọn ikọ miran to n wa ominira jakejado agbaye.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ladoja ní bí ìjọba kò bá fi ẹ̀lẹ̀ ṣe, ọ̀pọ̀ ajìjàgbara míì yóò dìde

Gẹgẹ bi Kitoye ti wi, "iwe akọsilẹ yii ni yoo wulo fun awọn olootọ ọmọ Yoruba to n kopa ninu ijijagbara fun ilẹ Yoruba.

Iwe yii lo n salaye awọn iroyin ti wọn nilo lati sisẹ ijagudu wọn, to si tun n tọ wọn sọna fun ilana ti wọn yoo tọ ati ohun ti ijijagbara naa wa fun."

Ko tan sibẹ, iwe iforukọsilẹ naa, lo tun n sọ nipa idi ti wọn se n jijagbara, eyi ti wọn lo nii nnkan se pẹlu iriri buruku ti ẹya Yoruba n la kọja lorilẹede Naijiria.

Amin iyasọtọ kan

"A kò sinmi lórí ọ̀rọ̀ Yoruba Nation, Sept 14 lá yọjú sí United Nation"

Asia Yoruba Nation

Awọn alatilẹyin idasilẹ Yoruba Nation ti jẹjẹ pe, awọn ko ni i sinmi lori ipolongo wọn fun idasilẹ orilẹ-ede naa, ti awọn si ti ṣetan lati gbe ọrọ awọn lọ siwaju ajọ United Nations ninu oṣu Kẹsan-an.

Ẹnikan lara awọn olori ẹgbẹ Ilana Oodua, Ọjọgbọn Wale Adeniran lo sisọ loju ọrọ yii ninu ijiroro kan to waye lori ayelujara Zoom lọjọ Iṣẹgun.

O ni pe iwaju ijoko Ajọ Agbaye yoo jẹ anfaani nla lati ṣalaye nipa Yoruba Nation fun awọn olori l'agbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọ Kẹrinla, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2021, ni ireti wa pe ipade kẹrindinlọgọrin ajọ UN yoo bẹrẹ nilu New York, orilẹ-ede America, ti yoo si pari ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

Ọjọgbọn Adeniran sọ pe "anfaani nla ni yoo jẹ fun wa lati fi ipa sọ ọrọ wa niwaju gbogbo aye.

"Fun ọsẹ kan gbako, ki gbogbo ọmọ Yoruba kaakiri agbaye yabo New York, ati ile ipade ajọ UN."

O ni oun yoo sọ fun Ọjọgbọn Banji Akintoye, to jẹ adari ẹgbẹ Ilana Oodua pe awọn ni lati darapọ mọ eto naa ni ilẹ America.

Lori lẹta ti ẹgbẹ naa kọ si ile ẹjọ ẹsun iwa ọdaran ni agbaye, International Criminal Court (ICC), Adeniran sọ pe awọn ti fi lẹta naa jiṣẹ, o si ti de ibi to yẹ ko de.

"Ṣugbọn nkan to ku fun wa lati ṣe ni pe ka tẹra mọ ariwo pipa, ki ile ẹjọ ICC le gba ọrọ wa ro, nitori pe eniyan ni awọn naa."