Yoruba Nation: Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ló ń fi ìbẹ̀rù hàn lórí ìwọ́de Yoruba Nation tí yóò wáyé ní Eko lónìí

Ọjọ pe, ọjọ ko ti iwọde Yoruba Nation ti ọpọ eeyan ti n fi oju sọna fun yoo waye.
Awọn ajijagbara to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba Nation si lo n se agbatẹru iwọde naa, ti Oloye Sunday Igboho ati alagba banji Akintoye si n lewaju wọn.
Ọjọ Satide, ọjọ Kẹta osu keje ọdun 2021 ti wọn ti kede saaju pe iwọde naa yoo waye nilu Eko ti wa ko bayii amọ ọpọ eeyan lo ti n kaya soke pe ki ni yoo sẹlẹ loni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "DSS yin ọta ìbọn 48 sí Adogan, kò sì kú, ni wọn bá fi ọmọ odó fọ lórí"
- Sunday Igboho ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí DSS pa
- Nnamdi Kanu áti IPOB burú ju Boko Haram, agbébọn lọ - Nasir El-Rufai
- DSS kò mú mi lọ́dọ̀ Guru Maharaji, èmi rèé n‘Ibadan, ẹ sinmi àhesọ ọ̀rọ̀ - Sunday Igboho
- Bí ìjọba Buhari bá yege láti pa mí ni, yóò ní ‘Unknown Gunmen’ ló wá pa mí - Sunday Igboho
- Kí ló dé tí DSS kó bàńtẹ́ òògùn, ba ilé Sunday Igboho jẹ́ lái fara pa?
- Ilé mi kọ́ ni àwọn DSS ti kó àwon ìbọ́n tí wọ́n pàtẹ- Sunday Igboho
- Àwọn ọmọ Yoruba lókè òkun ṣèwọ́de nílùú London torí Sunday Igboho
- "DSS, níbo ni ₦2m àti owó Euro, Dollar àti Pound Sterling tẹ kó nílé mi wà? "
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
Lati ọjọ ti ikede ti waye pe iwọde naa n bọ nilu Eko, ni awọn oniruuru iroyin ti ko fẹsẹ mulẹ ti n lọ lori ayelujara pe awọn eeyan kan ti n dunkoko lati kọlu awọn oluwọde naa.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn oluwọde yii ti n lọgun tẹlẹ pe iwọde alaafia ni awọn n gbe kiri, sibẹ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti sepade awọn akọroyin pe oun ko faaye gba iwọde naa lati waye.
Gẹgẹ bi Akeem Odumosu, tii se Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Eko se wi, ileesẹ oun ti hu gbọ pe awọn janduku kan ti n palẹmọ lati ja iwọde naa gba mọ awọn ajijagbara Yoruba Nation lọwọ.
O ni oun ko le la oju ohun silẹ, ki wọn da ilu Eko ru mọ oun lori gẹgẹ bo se waye lasiko iwọde Endsars eyi to mu ẹmi lọ, ti ọpọ dukia si tun bajẹ.
Sugbọn awọn ajijagbara naa ti wa fesi pada fun ọga ọlọpaa naa pe bo fẹ, bo kọ awọn n bọ nilu Eko lati wa se iwọde naa lọjọ Satide oni.
Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ti alagba Banji Akitoye ko sodi si ti fi ikede kan sọwọ sawọn akọroyin pe ẹgbẹ naa yoo tẹsiwaju pẹlu iwọde Yoruba Nation lọjọ Satide.
Bakan naa ni igun Sunday Igboho ti kede pe bi ikun lo ni oko ni, bi Pakute ni, ipade di ilu Eko lonii nibi tawọn yoo ti se iwọde.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki ti kede loju opo Facebook rẹ, asiko iwọde naa ni gbogbo agbaye yoo mọ ẹni to ni ilu Eko.
O ni aala yoo fi oko ọlẹ han laarin awọn ọlọpaa, Gomina Sanwo-Olu ati awọn ọmọ Yoruba to n bọ wa se iwọde.
Kaakiri ilẹ Yoruba ni awọn ajijagbara naa ti n lọ kaakiri lati se ipolongo fun idasilẹ orilẹede Yoruba Nation naa.
Lara awọn ilu ti wọn ti de ni Ibadan, Abeokuta, Osogbo, Akure, Ado Ekiti, Offa, Ilorin ati bẹẹ bẹẹ lọ
Amọ ibeere ti ọpọ ọmọ Yoruba n beere ni pe se nnkan yoo fara rọ nilu Eko loni, tii awọn ajijagbara naa ba yọju fun iwọde Yoruba Nation?














