Sunday Igboho: Àwọn ọmọ Yoruba lókè òkun ṣèwọ́de lọ iléeṣẹ́ aṣojú ìjọba Nàìjíríà ní London

Awọn oluwọde kan pẹlu aṣia wọn

Oríṣun àwòrán, Instagram/sunday igboho

Awọn ọmọ Yoruba to wa loke okun ṣe iwọde nileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede Naijiria ni ilẹ Gẹẹsi lọjọ Ẹti.

Iwọde naa da lori bi awọn oṣiṣẹ agbofinro DSS ṣe ya wọ ile eekan ọmọ Yoruba to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Sunday Igboho lọjọbọ.

Oniruru orin ẹhonu lawọn ọmọ Yoruba to ṣe iwọde naa kọ pẹlu awọn patako pelebe-pelebe ti wọn kọ akọle loriṣiriṣi si.

Lara awọn akọle wọn ni "Location 419.. #YorubaNationNow, "Yoruba Nation. No going back", "Sunday Igboho is a man of the people", "Oduduwa Nation must stand."

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Awọn oluwọde naa bu ẹnu atẹ lu bi awọn DSS ṣe kọlu ile naa ti wọn si ni eeyan ti ko fẹran wahala ni Sunday Igboho.

Ọkan lara awọn oluwọde naa torukọ rẹ n jẹ Peter Ọladele ṣalaye pe eredi iwọde wọn ni lati fi to awọn alaṣẹ ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria naa leti peo to gẹẹ.

"Ẹ wo awọn iwa ọdaran ti awọn ọdaran darandaran kan n hu kiri; awa o ni dakẹ. Sunday Igboho kii ṣe ọdaran."

Oluwọde miran, Grace Dada ṣalaye pe "ki ni Igboho ṣe fun ijọba apapọ? Gumi wa nibẹ to n fidigbodi pẹlu awọn agbebọn, ki lo de ti wọn ko lọ fi panpẹ ofin mu u.

Àkọlé fídíò, Soiless Farming: Samson Ogbole ní táwọn irè oko bá fara kan ilẹ̀, ló ń kó àrùn bá wọn

Ni Ọjọbọ lawọn oṣiṣẹ DSS atawọn agbofinro kan wọ ile Sunday Igboho ti wọn si pa eeyan meji; bakan naa ni wọn ko oriṣiriṣi nnkan nibẹ.