Yoruba Nation: Igun Sunday Igboho ní Sátidé ní yóò sọ ẹni tó nìlú Eko láàrin ọmọ Yorùbá àti ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki
Igun awọn ajijagbara to n tẹle Sunday Igboho lẹyin ti n ke tantan tan pe iwọde Yoruba Nation ti wọn fẹ se nilu Eko yoo waye lọjọ Satide,
Agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki lo fi ikede yii sita loju opo Facebook rẹ.
Koiki ni lootọ ni ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Eko ti fi ikede sita pe oun ko fẹ ri awọn oluwọde Yoruba Nation amọ awọn ajijagbara naa ni lori irọ ni.
Igun Sunday Igboho ni asọrọ sẹ ni awọn, awọn ko si le sọrọ tan ki awọn wa ni awọn ko ni se bẹẹ mọ nitori ọmọ ọkọ ni awọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
- "Sunday Igboho, Banji Akitoye, ẹ rìn jìnnà sójú pópó Eko fún ìwọ́de Yoruba Nation"
- Afenifere figbe bọnu pé ìkọlù sí òmìnira àti ẹ̀tọ́ láti sọ̀rọ̀ ti padà dé
- Ìbọn àti nǹkan ìjagun ni Igboho kó pamọ sílé ló jẹ kí á yabo ilé rẹ̀ - DSS
- Gani Adams tutọ́ sókè fójú gbà lórí ìkọlu sílé Sunday Igboho
- Níbo ní Sunday Igboho wà lẹ́yìn ìkọlù síle rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ń bèèrè
Nitori naa, wọn ni awọn yoo tẹsiwaju pẹlu iwọde Yoruba Nation naa boya Sunday Igboho tẹle awọn tabi ko si nibẹ.
Bẹẹ ba si gbagbe, ẹgbẹ Ilana Omo Oodua labẹ akoso alagba Banji Akitoye naa ti fi atẹjade kan sita ni Ọjọbọ pe awọn yoo tẹsiwaju pẹlu iwọde naa.
Agbẹnusọ fun Sunday Igboho ni "Mo gbọ pe Kọmisana Ọlọpaa ni Eko kede pe a ko gbọdọ wa se ikede Yoruba Nation lọjọ Satide, ọjọ Kẹta osu yii.
Ẹ jọọ, ẹ ba wa sọ fawọn ọlọpaa Eko pe a n bọ, a si ti de tan, ki wọn maa reti wa.
Ọjọ naa si la mọ ẹni to ni Eko laarin awọn ọmọ Yoruba ati gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati awọn ọlọpaa.
Ọjọ Satide yii naa la mọ bi ikun lo ni oko, bi pakute ni, a pade ni Eko lọjọ Satide fun iwọde naa, ipade di ọhun."
Bakan naa ni agbẹnusọ fun Sunday Igboho ni "bi gbogbo nnkan yoo ba bajẹ, ko kuku bajẹ lọjọ Satide, o ku sọwọ wọn lati jẹ ka se iwọde pẹlu putu wa tabi bẹẹ kọ.
Ninu kẹ jẹ ka se iwọde alaafia tabi da igboro ru, o ku si yin lọwọ, amọ gbogbo ohun to ba sẹlẹ, ileesẹ ọlọpaa Eko ni kẹ mu lori rẹ."
O wa kede pe aago mẹsan aarọ ni iwọde naa yoo gbera ni gbagede Gani Fawehinmi ladugbo Ojota nilu Eko.
O si rọ gbogbo awsn ajijagbara fun Yoruba Nation lati peju lọpọ yanturu si ibi iwọde naa.
Saaju la ti fi to yin leti pe ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Eko ti fi atẹjade kan sita pe oun ko fẹ kofiri awọn ajijagbara naa rara nilu Eko.
- Àwọn DSS àti ṣọ́jà ló kọlu ilé mi, mo fojú mi kòrókòró rí wọn - Sunday Igboho
- Àwọn ológun Nàìjíríà pẹ̀lú agbésùmọ̀mí ilẹ̀ òkèèrè ló kọlu ilé Igboho - Akintoye
- Àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara Yoruba fọnmú lórí ìkọlù sílé Sunday Igboho
- Ẹ̀jẹ̀ kúnlẹ̀ nílé Sunday Igboho, ẹ̀mí méjì bọ́ lásìkò tí afurasí Sọ́jà kọlu ilé rẹ̀
- Sunday Igboho, ṣe sùúrù díẹ̀ lórí ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko - Olugbon ń lọgun
- Afurasí ‘Sọ́jà’ kọlu ilé Sunday Igboho lóru mọ́jú, òkú ṣùn, dúkìá bàjẹ́


















