Sunday Igboho: Sunday Igboho ní àwọn DSS àti ṣọ́jà ló kọlu ilé òun, èèyàn méjì ni wọ́n sì pa

Ọkan lara awọn ọkọ ti wọn bajẹ nile Sunday Igboho

Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho ti sọ pe awọn oṣiṣẹ DSS ati awọn ologun lo wa nidi iṣẹlẹ ikọlu to waye ni ile rẹ nilu Ibadan loru Ọjọbọ mọju.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC lori bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, Oloye Sunday Igboho ni nnkan bii agogo kan abọ ni iṣẹlẹ naa waye ti oun si n gbọ iro ibọn lakọlakọ ti awọn afurasi oṣiṣẹ DSS ati ọmọogun naa si n pariwo oruks oun lati bọ sita.

"Mo yọju loju ferese, mo ri wọn ninu aṣọ DSS ati aṣọ ologun. Mo si wo o pe ki ni mo ṣe ju pe mo ja fun awọn mọlẹbi mi to jẹ Yoruba lati bọ lọwọ awọn agbebọn to n pa wọn to n fipa ba awọn obinrin wọn lo pọ.

Gbogbo iwọde ti mo si n ṣe lo jẹ iwọde alaafia"

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Oloye Sunday Igboho ni idi ti oun fi gbe igbesẹ ati ja fun iran Yoruba ni pe ijọba ti kuna ninu ojuṣe rẹ lati daabo bo awọn eeyan ilẹ Yoruba.

O ni oun wa ninu ile lasiko ti awọn agbebọn naa wọ ile oun ati pe eeyan meji ni wọn pa.