Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ OYC, YWC ní ìwọ́de July 3 yóò wáyé l‘Eko, bó ti wù kẹ kọlu Igboho tó

Ile Sunday Igboho

Ni oru Ọjọbọ ni iroyin sọ pe awọn eeyan kan ti wọn wọ aṣọ ologun ya wọ ile gbajumọ aṣiwaju fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti ṣe ọpọlọpọ ọṣẹ lasiko ikọlu naa.

Gẹgẹ bi ohun ti akọroyin BBC News Yoruba to lọ sibẹ se fi mulẹ, ọpọlọpọ ọkọ ati dukia miran lo ba lọ. Bakan naa ni ẹjẹ wa lawọn agbegbe kan ni ile naa.

Pẹlu bi eekan ọmọ Yoruba yii ṣe n gbaradi fun iwọde nla kan ni ilu Eko lọjọ Satide ọjọ kẹta oṣu keje ọdun 2021 fun idasilẹ orilẹede Yoruba ti wọn da pe ni "Yoruba Nation", ọpọ lo n woye pe ṣe irufẹ iṣẹlẹ bayii ko ni mu idiwọ ba iwọde naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Comrade Oluyi Akintade Tayọ ti ẹgbẹ oodua Youth Coalition ṣalaye pe, ikọlu lati ibikibi ko lee da iwọde naa duro.

O ni yoo wulẹ tubọ mu ki agbara pọ fun awọn sii ni.

Ọgbẹni Akintade Tayọ ṣe e lalaye pe, inu gbogbo awọn to n ja fun ijijagbara ilẹ Yoruba lo bajẹ si iṣẹlẹ naa ati pe bi awọn to gbe igbesẹ ikọlu naa ba lero pe wọn yoo fi dun kuku laja mọ awọn, ko lee ri bẹẹ rara.

"Ko si ibi to gba jọra, ẹni to jẹ Baba fun gbogbo wa, Ọjọgbọn Akintoye ti sọ pe ko si ayipada lori iwọde naa, eyi to fihan pe bi o ti le wu ki atako waye to, ooyẹ kankan ko le yẹ iwọde ilu Eko naa."

Ile Sunday Igboho

Ninu ọrọ tirẹ, eekan ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọ Yoruba miran, Dokita Amos Akingba ti ẹgbẹ Yoruba World Congress ṣalaye pe, dipo ki awọn alaṣẹ o tẹti si igbe araalu, ki wọn si wa nnkan ṣe si ẹhonu awọn eeyan amọ ohun to lee tubọ bi idide tako ijọba ati ipe fun ipinya ni wọn n ṣe.

Ninu ọrọ rẹ, o ni kii ṣe ilẹ Yoruba nikan ni ẹhonu yii ti n wa leyi to fihan pe ijọba ni iṣẹ lati ṣe lati tẹti si ẹhonu araalu.

Awọn to sun mọ oloye Sunday Igboho ṣalaye pe yatọ si dukia, ẹmi pẹlu sọnu sinu ikọlu naa.