Sunday Igboho: Ọmọ odó làwọn agbébọn fi fọ́ ìlẹ̀kùn wọlé gbẹ̀mí, ba dúkìá jẹ́ nílé ajìjàgbara

Ile Sunday Igboho

BBC Yoruba lọ sile Oloye Sunday Igboho to wa ni adugbo Soka, nilu Ibadan ni aarọ Ọjọbọ lati mọ bi ikọlu si ile rẹ se waye.

Bẹẹ ba gbagbe, a ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe awọn afurasi Sọja kan ya bo ile ajijagbara fun ilẹ Yoruba naa ni deede aago kan abọ oru mọju oni.

Nigba ta kan sile naa, a ri pe ọpọ dukia lo bajẹ ninu ile ọhun eyi ti apapọ owo wọn le ni aimọye biliọnu naira.

Bi o tilẹ a ko ri Igboho ninu ile, sibẹ, ko si ẹnikẹni to setan lati sọ ibi ti ajijagbara naa wa, amọ iroyin kan ti ko fi ẹsẹ mulẹ ni se lo sadede poora lasiko ti awọn agbebọn naa de.

A ba awọn eeyan kan ninu ile ọhun, ti wọn si mu wa kaakiri lati foju se mẹrin ọsẹ to waye nibẹ amọ ko si ẹnikẹni to ba wa sọrọ nibẹ.

Ninu irinajo wa yika inu ati agbala ile Sunday Igboho naa, a gbọ itakurọsọ ti awọn eeyan to wa nibẹ n se, ti wọn si n sọ laarin ara wọn pe eeyan marun lo ba isẹlẹ naa rin.

Ile Sunday Igboho

Bakan naa la ri abawọn ẹjẹ ni ọna mẹta ninu ile naa, eyi to fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan fara gbọgbẹ tabi ki ẹmi wọn bọ ninu isẹlẹ naa.

Bakan naa la ri pe ọpọ awọn ferese to wa ninu ile naa, ti wọn jẹ kikida digi ni wọn fọ, ta si ri afọku igo nilẹ Kaakiri pẹlu.

A tun foju ganni awọn aworan lorisirisi ti wsn fọ mọlẹ, ti wọn wo tabili, ti awọn ilẹkun kan si fara han pe wọn fọ wọn.

Koda, a tun ri ọmọ odo kan nilẹ niwaju ile Sunday Igboho, eyi ta gbọ pe awọn agbebọn naa lo lati fọ ilẹkun ẹnu iloro ile wọle, ti wọn si tun fi fọ oju ferese ati ara ile.

Awọn mọto nla nla la ri tawọn ferese wọn ti fọ, to fi mọ awọn ọkọ olowo iyebiye bii G-Wagon, Prado jeep, to fi mọ bọọsi ti wọn tẹ orukọ Yoruba Nation si lara.

ỌkọYoruba Nation ti wọn bajẹ

Bakan naa la ri awọn aloku ọta ibọn nilẹ niwaju ile naa to wa nilẹ ilẹ.

Awọn eeyan ta ba ninu ile Sunday Igboho naa ni gbogbo awọn eeyan ti wọn n gbe ninu ile ọhun ni awọn afurasi Sọja to wa naa ko lọ, to fi mọ obinrin to n se ounjẹ fun wọn.

Igba akọkọ kọ ree ti ikọlu yoo maa waye sile amọ ibeere ti ọpọ n beere ni pe nibo ni Sunday Igboho wa lasiko ti iklu tii fi n waye.

Ọmọ odo ti wọn fi fọ ilẹkun wọle