Sunday Igboho: Ọkọ̀ bọ́ọ́sì àti Taxi láwọn jàǹdùkú tó jólé gbé wá

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe oun ti gba abọ awọn osisẹ oun nipa isẹlẹ bi ina se jo ile Oloye Sunday Igboho.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi, lo fidi isẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan lọjọ Isẹgun
Ileesẹ ọlọpaa ni iroyin to tẹ oun lọwọ lo fidi rẹ mulẹ pe awọn janduku to wa jo ile Igboho lo wa pẹlu ọkọ bọọsi ati taxi.
- N kò le ṣàtìlẹyìn fún arúfin láti tán ìṣòro ètò ààbò - Seyi Makinde
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Kìí ṣe àgbẹ̀ nìkan ni ọ̀daràn darandaran n pa, wọ́n n pa àwa Fulani nàá - Ààrẹ Miyetti Allah
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Oyo fikun pe awọn janduku naa yinbọn soke ni ọpọ igba, ki wọn to jo ile Igboho to wa ladugbo Soka, nilu Ibadan.

O fikun pe ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti bẹrẹ iwadi kikun nipa isẹlẹ naa, eyi to waye ni deede aago mẹta oru
Mọ́tò mẹ́ta làwọn jàǹdùkú gbé wá sun ilé Sunday Igboho - Ará àdúgbò

Ikọ iroyin BBC Yoruba ti balẹ sile ajafẹtọ iran Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho ti ile rẹ jona mọjumọ ọjọ Aje.
Abẹwo BBC Yoruba si ile to jona ọhun fihan pe laarin aago meji si mẹta oru ni isẹlẹ ọhun waye.
A tun gbọ pe ile to jona naa jẹ ile atijọ Sunday Igboho, eyi to ti gbe tẹlẹ ri, to si wa ni adugbo Soka nilu Ibadan, nibi to sunmọ ile to n gbe lọwọ lọwọ.
Ọkan lara awọn olugbe adugbo ti Sunday Igboho n gbe tẹlẹri ni agbegbe Soka sọ fun BBC Yoruba wi pe, awọn eeyan kan lo dede wa dana sun apa ibi kan ninu ile naa.

Wọn fi idi ọrọ mulẹ wi pe, o to ọkọ mẹta ọtọọtọ ti awọn eeyan to sisẹ ibi yii gbe wa, lati dana sun ile naa.
Lara nnkan ti wọn ri lẹyin iṣẹlẹ naa lẹba ile to jona ọhun ni kẹẹgi epo bentiro ati awọn ọta ibọn.
Bakan naa ni iwadii fi idiẹ mulẹ wi pe, ẹmi ẹnikẹni ko ba iṣẹlẹ naa lọ, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ dukia to wa ninu ile naa lo jona kanlẹ.

Pupọ ninu awọn to n gbe ile naa tẹlẹri, ni wọn ti ko lọ si ile tuntun nibi ti Sunday Igboho ko lọ ni agbegbe Soka bayiii.
Kí ló fa ìjàmbá iná nílé Sunday Igboho lóru mọ́jú òní?

Oríṣun àwòrán, Koikimedia
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ijamba ina ti waye ni ile gbajugbaja ajafẹtọ ọmọ Yoruba nii, Oloye Sunday Adeyemo, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho.
Ile Igboho naa lo wa ni adugbo Soka, nilu Ibadan.
Ijamba ina yii, gẹgẹ ba se gbọ, waye lọjọ Aje tawọn Gomina iwọ oorun guusu ilẹ yi fẹnuko lẹyin ipade to waye ni Akure, pẹlu awọn olori Fulani lati dẹkun wahala to n waye lagbegbe naa
Ohun to ṣokunfa ina yi ko ye ẹnikankan ṣugbọn ninu fọnran fidio kan ti BBC Yoruba ri, niṣe lawọn eeyan kan n ṣe afihan bi ina ti ṣe jo ile naa, to si ba ọpọlọpọ duki Sunday Igboho jẹ.

Oríṣun àwòrán, Koikimedia
Bi o tilẹ jẹ pe a ko tii le fi aridaju fidio yii mulẹ ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ohun to wa ninu rẹ ti sọ, lẹyin ti ina ọba lọ ni alẹ ọjọ Aje ni isẹlẹ ina ṣadede ṣẹyọ nibẹ.
Wọn ni awọn panapana lo sare wa lati dẹkun ina naa ṣugbọn ko si aridaju pe eeyan kankan farapa tabi ku ninu ijamba ina yii.
Loju opo Sunday Igboho yala ni Instagram tabi Twitter ko ti fi ọrọ sita nipa iṣẹlẹ yii.
Ni kete ti a ba ti ri aridaju bi ijamba ina naa ṣe waye, a o fi to yin leti, ẹ maa ba wa kalọ.


















