South West Governors-Miyetti Allah meeting: Àṣà dída ẹran níbikíbi di èèwọ̀

Koko mẹwa ti wọn fẹnu ko le lori nibi ipade awọn gomina ati Miyetti Allah
Ipade awọn gomina nilẹ Yoruba ati ẹgbẹ awọn darandaran Miyetti Allah ti waye lọjọ Aje, to si ti wa sopin pẹlu.
Atẹjade kan ti wọn fisita lẹyin ipade naa, salaye nipa awọn ohun tawọn gomina ilẹ Yoruba ati ẹgbẹ Miyetti Allah fi ẹnu ko le lori.
- Sunday Igboho yarí lórí àwọn ‘ọ̀rọ̀ ìbajẹ́’ tí Babafemi Ojudu kọ nípa rẹ̀
- Ṣọ́jà àti ikọ̀ aláàbò ESN tí Nnamdi Kanu, ṣíná ìbọn fúnra wọn Gómìnà Uzodinma òfin ìséde kalẹ̀
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- N kò le ṣàtìlẹyìn fún arúfin láti tán ìṣòro ètò ààbò - Seyi Makinde
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Kìí ṣe àgbẹ̀ nìkan ni ọ̀daràn darandaran n pa, wọ́n n pa àwa Fulani nàá - Ààrẹ Miyetti Allah
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
Atẹjade naa ti wọn fi sita nilu Akure nibi ti ipade naa ti waye Dokita Kayode Fayemi, tii se alaga ẹgbẹ awọn gomina lorilẹede Naijiria fọwọsi.

Koko abọ ipade awọn gomina nilẹ Yoruba ati ẹgbẹ Miyetti Allah:
- Ko si ẹni to ni ki ẹnikẹni kuro ni ipinlẹ kankan amọ gbogbo eeyan lo gbọdọ fi ọwọ sowọpọ lati gbogun ti iwa ọdaran
- Ko ni si ẹran dida mọ ni alẹ lati akoko yii lọ
- Iwa kawọn ọmọde maa da ẹran lewu fun eto aabo nitori naa, ofin ti de iwa yii
- Dida ẹran tabi gbigbe inu igbo ọba lọna to lodi sofin ni wọn bu ẹnu atẹlu
- Asa dida ẹran jẹ nibikibi gbọdọ dawọ duro lati dena laasigbo laarin awọn agbẹ ati darandaran
- Ẹgbẹ MACBAN gbọdọ tẹwọgba ilana dida ẹran tigbalode nipa nini ibudo ọsin ẹran lọna ati dena vi maalu wọn se maa n jẹ kiri
- Asẹ ti gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu pa ni awọn ileesẹ iroyin si gbọ, o kan pasẹ pe ki awọn to n gbe inu igbo ọba nipinlẹ Ondo lọna to lodi sofin fi ibẹ silẹ ni
- Ẹgbẹ darandaran MACBAN naa n fara gba ninu iwa ijinigbe ati ati eto aabo to mẹhẹ, to si n fẹ ki alaafia jọba
- Gbogbo awọn ọdaran lọwọ gbọdọ tẹ, ki wọn si jiya ẹsẹ wọn, lai naani ilu abinibi wọn, ipo kanka ti wọn wa ati ipo wọn lawujọ
- Awọn osisẹ alaabo ti n tiraka lati mu adinku ba aifara rọ eto aabo ni Naijiria amọ wọn gbọdọ fikun aayan wọn ninu ogun ti wsn n gbe ti iwa ọdaran
- O yẹ ki ajọsepọ wa pẹlu ẹgbẹ awọn darandaran lati fi ẹsẹ alaafia ati aabo mulẹ, ki ifọwọsowọpọ le wa nidi gbigbe ogun ti iwa ọdaran lawujọ
- Aabo ati idẹrun awọn ọmọ Naijiria ni koko ojuse ijọba gẹgẹ bo se wa ninu ofin ilẹ wa tọdun 1999
- Awọn alẹnulọrọ mu isọkan ati orilẹede Naijiria ti ko ni iyapa ninu lọkunkundun
- Aifararọ eto aabo jẹ ipenija to n ba gbogbo ẹkun ni Naijiria finra, ko si mọ lọdọ ẹya tabi ẹkun kan, isẹ ajumọse gbogbo wa si ni lati rẹyin rẹ
- Awọn ijọba ni ẹlẹkajẹka gbọdọ mu eto aabo lọkunkundun, ki wọn si maa sugba awọn osisẹ eleto aabo, ki okun aabo le yi daindain si.
Kìí ṣe àgbẹ̀ nìkan ni ọ̀daràn darandaran n pa, wọ́n n pa àwa Fulani nàá - Ààrẹ Miyetti Allah

Aarẹ ẹgbẹ darandaran Miyetti Allah, Mohammed Kirowa to bawọn to peju sibi ipade to n waye ni ọfiisi Akeredolu lọwọ lọwọ bayii, naa ti sọrọ nipa iwa ika tawọn darandaran n hu.
Kirowa lasiko to n ba ipejọpọ awọn ọlọpaa ati gomina ilẹ Yoruba sọrọ sọ pe awọn daran-daran ti pa awọn Fulani naa ri.
"Kii ṣe awọn agbẹ nikan ni wọn n pa, wọn n pa awọn Fulani naa, koda, ọpọlọpọ Fulani ni wọn ti ji gbe, ti wọn pa. Gbogbo rẹ si la koro oju si."
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
Bakan naa ni Korowa fikun pe Baba oun ti wa ni ilẹ Yorùbá lati ọdun marunlelọgọrun sẹyin, ilẹ Yoruba si ni wọn fi ori oun sọlẹ si.
Awọn gomina ati Miyetti Allah bẹrẹ ipade, ohun ti Akeredolu sọ ree:

Ipade apero ti n lọ lọwọ nilu Akure laarin awọn gomina ilẹ Yoruba ati awọn adari ẹgbẹ daran-daran, Miyetti Allah.
Ipade naa ko ṣẹyin bi gomina Rotimi Akeredolu ṣe fun awọn afurasi ọdaran daran-daran to n ṣọṣẹ ni inu igbo nipinlẹ Ondo, ni gbedeke lati kuro nibẹ.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2021, ni gbedeke naa pari.
Aṣẹ naa waye nitori bi awọn daran-daran kan ṣe n fi iṣẹ wọn boju ṣiṣẹ ibi, ti wọn n pa eeyan, ji eeyan gbe, digun jale, ti wọn si tun n fipa ba obinrin lopọ.

Nigba to n sọrọ nibi ipade naa, Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi sọ pe ko si ẹni to fẹ ẹ le awọn Fulani kuro nilẹ Yoruba.
O ni "Ko si ẹni to fẹ ẹ le Fulani jade kuro nilẹ yoruba, ile yin re e .
"Awọn ọdaran la fẹ ẹ le jade kuro laarin awọn daran-daran Fulani, kii ṣe lati le awọn Fulani to ti n gbe nibi fun ọpọlọpọ ọdun."

Lara awọn to peju sibi ipade naa ni awọn olori ileeṣẹ eto aabo nipinlẹ Ondo, ati awọn ipinlẹ to mu le tii.

Ṣaaju ipade naa, Gomina Akeredolu, Kayode Fayemi ti ipinlẹ Ekiti, ati akẹẹgbẹ wọn lati ipinlẹ Jigawa, Abubakar Badru pẹlu Abubarka Bagudu ti ipinlẹ Kebbi, ti ṣe ipade ikọkọ kan.
- Ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Oduduwa ló mú kí Yorùbá wá kọlu Fulani ní Igangan - Ọmọ Seriki Fulani
- Báyìí ni àwa àti Sunday Igboho ṣe rìnrìn àjò láti Ibadan lọ sí Igangan"
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Ó tó gẹ́! Ọ̀gá Ọlọ́pàá pàṣẹ pé kí Kọmísọ́nnà Oyo mú Igboho wà sí Abuja













