Sunday Igboho: Ṣé Igboho ṣetán láti ṣe ìpàdé pẹ̀lú Seyi Makinde àti ọlọ́pàá?

Oríṣun àwòrán, Facebook Sunday Igboho/OfficialSeyiMakinde/
Ọrọ aawọ to n waye lagbegbe Ibarapa ni ipinlẹ Oyo ti n ṣebi ẹni niyanju bọ diẹdiẹ pẹlu bi ijọba ti ṣe fẹ ṣepade pẹlu ọga ọlọpaa ati awọn lọba lọba nibẹ.
Afojusun ipade yii, gẹgẹ bi alaye ti igbakeji alaga igbimọ lọbalọba Oyo, Olugbọn tilu Orile-Igbọn, Oba Francis Olusola Alao ṣe sọ, ni lati da alaafia pada si agbegbe ọhun.
Lẹnu lọọlọ yi, laasigbo n waye pẹlu bi gbajugbaja ajafẹtọ Yoruba kan, Sunday Igboho ṣe lọ silu Igangan, lati kilọ fawọn ajinigbe, ọdaran ati apaniyan to wa lgbegbe Ibarapa lati so ewe gbejẹ mọ ọwọ.
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Ó tó gẹ́! Ọ̀gá Ọlọ́pàá pàṣẹ pé kí Kọmísọ́nnà Oyo mú Igboho wà sí Abuja
- Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí
- Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan
- ''Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kò bẹ̀rù idúnkokò mọ́ni iléeṣẹ́ ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ àwọn Fulani darandaran''
Eyi ko ṣẹyin bi awọn eeyan ṣe n ke irora lori ẹsun ipaniyan ati ijinigbe to n waye lati ọwọ awọn ọdaran kan laarin awọn ẹya Fulani to tẹdo si agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Iroyin naa ni ọba alade naa ni ikọ lati ọdọ Gomina, omiran lati ọdọ ọga ọlọpaa ti Kọmisana tuntun Ngozi Onadeko yoo dari, ni yoo wa nibi ipade naa pẹlu ikọ asoju awọn lọbalọba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọkọ̀ akẹ́rù Dangote ya wọ ibùdó ìtajà ní Akungba Akoko, èèyàn mẹ́jọ dèrò ọ̀run
- Ọ̀nà àbáyọ mẹ́wàá rè é fún aláboyún tí kò bá rí oorun ṣùn
- Ṣé lọ́ọ̀tọ̀ ní àkúdááyà wà? ẹ̀ wo ìrírí àwọn tó rí ènìyàn wọn tó kú láàyè
- Wo nkan tó mú òṣìṣẹ́ akólẹ̀-kódọ̀tí fún LAWMA kàgbákò ikú l'ẹ́nu iṣẹ́ nípìnlẹ̀ Eko
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
- Adigunjalẹ̀ kolu àwọn sójà ní Ondo,wọ́n yìnbọn lú wọ́n ní àyà àti ní apá
''Mo n lọ si Ibarapa lọjọ Aiku lati lọ ṣe ipade pẹlu awọn lọbalọba Ibarapa. Kọmisana ọlọpaa yoo wa nibẹ, Aṣoju ọga ọlọpaa ati aṣoju ijọba naa yoo wa nibẹ''
''Alaafia la fẹ lagbegbe naa. Mo n lọ si ipade yii gẹgẹ bi igbakeji alaga igbimọ lọbalọba. Mo si ti sọ fun gbogbo awọn lọbalọba ni Ibarapa pe ki wọn peju sibẹ''
Ọba alaye naa tẹsiwaju pe ''igbesẹ n waye lati pari aawọ yi ni Tede, Agọ Arẹ ati agọ Amodu ni ijọba ibilẹ Atisbo. Emi ni mo n dari gbogbo eto yii ta si fẹ kawọn eeyan jẹ ki alaafia jọba''
Amọ ibeere to n gba ẹnu awọn eeyan ni pe se wọn ti gba Sunday Igboho sẹyin ninu ipade yii ni?
bakan naa ni wọn n beere pe se Igboho yoo lọ sibi ipade naa, ka si mọ boya gbogbo rogbodiyan naa yoo jẹ rodo, lọ mumi lẹyin ipade yii?
Sugbọn ọpọ ni o see se ki wọn ma pe Igboho sibi ipade naa nitori ọga patapata ọlọpaa ti paṣẹ saaju pe ki wọn mu Sunday Igboho wa si Abuja lati wa jẹjọ niwaju ile ẹjọ.
Titi di ba ṣe n ko iroyin yii jọ, ko si aridaju pe Kọmisana ọlọpaa ni Oyo ti tẹle aṣẹ ti ọga ọlọpaa pa.

Bakan naa ni iroyin kan ni awọn olori Fulani to wa ni Igangan ni oun ti sa asala fẹmi oun lẹyin ti awọn kan dana sun ile Seriki.
Ko daju boya awọn olori Fulani yoo wa nibi ipade yii ṣugbọn bi nkan ba ti ṣe n lọ si, gbogbo rẹ la o maa mu tọ yin wa.



















