Akungba Akoko Accident: Fásitì Adekunle Ajasin ṣún ìdánwò síwájú láti bọ̀wọ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kú

Ijamba to waye ni Akungba Akoko

Oríṣun àwòrán, Twitter/@gbemidennis

Awọn alaṣẹ fasiti Adekunle Ajasin, Akungba-Akoko, ti paṣẹ pe ki ileewe naa di titi pa ni kiakia.

Ninu ikede ti Adele Akọwe ileewe naa, Opeoluwa Akinfenwa fi sita lọjọ Aiku, awọn alasẹ sọ pe igbesẹ naa waye nitori bi awọn akẹkọọ ṣe ṣe iwọde.

Wọn si ti fun gbogbo akẹẹkọ ni gbedeke aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2021, lati fi ọgba ileewe silẹ.

Iroyin sọ pe awọn akẹkọọ ati awọn ọdọ ilu Akungba-Akoko tu jade ni ọjọ Aiku, lati fi ẹhonu han nitori ijamba ọkọ akẹru to pa awọn eeyan lọjọ Satide.

Ijamba naa ni iroyin sọ pe o waye lasiko ti ọkọ nla kan to ko simẹnti to jẹ ti ileeṣẹ Dangote, sọ ijanu rẹ nu, to si yawọ awọn ṣọọbu kan ni ẹgbẹ fasiti Adekunle Ajasin to wa nilu naa.

Awọn akẹkọọ fasiti naa wa lara awọn eeyan to padanu ẹmi wọn sinu ijamba naa.

Ọkọ̀ akẹ́rù Dangote ya wọ ibùdó ìtajà ní Akungba Akoko, èèyàn mẹ́jọ dèrò ọ̀run

Ijamba to waye ni Akungba Akoko

Oríṣun àwòrán, @Advisers_corner

Adura ti ọpọ eeyan maa n gba ni pe ki ọba oke mase jẹ ka rin lọjọ ti ebi yoo pa ọna.

Amọ eyi ko ri bẹẹ fun awọn eeyan mẹjọ kan nilu Akungba Akoko nipinlẹ Ondo lọjọ Abamẹta nigba ti wọn ko agbako ijamba ọkọ.

Gẹgẹ bi iroyin to de setigbọọ ikọ iroyin BBC Yoruba ti wi, o kere tan, eeyan mẹjọ lo kagbako iku ojiji lasiko ijamba ọkọ naa to waye ni deede aago mẹfa irọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa fikun pe awọn akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin naa wa lara awọn eeyan to dero ọrun ọhun, ti ọpọ eeyan miran si fara pa.

Ijamba to waye ni Akungba Akoko

Oríṣun àwòrán, @KingMikasaa

Ohun to fa sababi isẹlẹ naa ni ti ọkọ akẹru kan to jẹ tileesẹ Dangote ti ijanu rẹ sọsẹ silẹ, to si ya lọ kọlu awọn eeyan to wa lawọn ọja ati ibudo itaja to wa lẹba fasiti Adekunle Ajasin naa.

Ilu Ikare Akoko ni wọn ni ọkọ akẹru ọhun ti n bọ, asiko to si n sọkalẹ lati ori oke to wa lẹba fasiti naa ni bireeki rẹ sọsẹ silẹ, to si kọlu ọpọ eeyan.

Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ ni "Gbogbo awọn akẹkọọ to wa nibudo itaja lo kọlu, to fi mọ awọn eeyan to n rin lẹba oju ọna.

Iwadii fihan pe awọn akẹkọọ to fori sọta ijamba naa ni wọn n mura idanwo ti yoo waye lọjọ Aje silẹ, ti wọn si lọ sibudo itaja naa lati lọ se awọn ẹda iwe ti wọn nilo.

Ijamba to waye ni Akungba Akoko

Oríṣun àwòrán, @KingMikasaa

Wo igbesẹ ti fasiti Adekunle Ajasin gbe lori isẹlẹ yii:

Wayi o, adele akọwe agba fun fasiti Adekunle Ajasin, Opeoluwa Akinfemiwa ti fi atẹjade kan sita ni kete ti isẹlẹ naa waye.

Ninu atẹjade naa si lo ti wa pasẹ pe ki wọn ti ẹnu ọna abawọle sinu ọgba ile ẹkọ naa to wa loju titi.

Atẹjade naa, to kẹdun pupọ pẹlu awọn ẹbi akẹkọọ ti isẹlẹ iku ojiji naa kan, wa jẹjẹ pe ijọba ipinlẹ Ondo ati awọn oludari ile ẹkọ fasiti naa ti n wa ọna abayọ sirufẹ isẹlẹ yii lọjọ iwaju.

Bakan naa ni wọn kede pe wọn ti sun idanwo akẹkọ to yẹ ko bẹrẹ lọjọ Aje siwaju di ọjọ miran, ọjọ re nitori isẹlẹ asekupani ọhun, lọna ati bu ọwọ fawọn akẹkọọ to papoda.