Sunday Igboho vs Fulani: Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho, Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán-Seriki Fulani

Eekan ọmọ Yoruba ti ọrọ nipa rẹ n ja ranyinranyin lori ọrọ awọn Fulani lagbegbe Ibarapa ni ipinlẹ Ọyọ, Oloye Sunday Igboho ti sọ pe oun n pada lọ si ibuba awọn Fulani lagbegbe naa lọsẹ to n bọ.
Sunday Igbohoto ba awọn eeyan Ibarapa sọrọ lasiko to ko awọn ọmọlẹyin rẹ lọ ṣe ohun to pe ni jijawe o to gẹẹ fawọn Fulani to n wa nidi ijinigbe ati ipaniyan lagbegbe naa.
Eyi waye lẹyin gbendeke ọjọ meje to fun awọn Fulani naa lati fi ko aasa wọn kuro lagbegbe naa.
- Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí
- Gbèǹdéke ku àsìkò díẹ̀, Seriki Fulani fohùn ránṣẹ́ sí Sunday Igboho
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
- N kò jà fún ìṣọ̀kan Yorùbá láti wá ipò tàbí orúkọ - Sunday Igboho
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ lórí ohun tó kan fún ilẹ̀ Yorùbá lọ́dún 2021
- Ẹ̀yin èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo, mìmì kan kò lè mì yín lónìí- Makinde
Iroyin to tẹ wa lọwọ ṣalaye pe Oloye Igboho kaakiri gbogbo agbegbe naa pẹlu ọwọ ero lẹyin lati kilọ fawọn ajinigbe nibẹ eleyi ti omilẹgbẹ awọn ọmọ Ibarapa baa rin pọ.
Amọṣa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ lati ọdọ ikọ oloye Igboho, wọn ni wọn ko de gaa ile Seriki Fulani.
Nitori pe: gẹgẹ bi o ṣe sọ, Igboho ni pe oun pẹlu kọmiṣọnna ọlọpaa tuntun ni ipinlẹ Ọyọ, Ngozi Onadẹkọ ni yoo jọ lọ sọdọ Seriki Fulani atawọn fulani rẹ lọjọ iṣẹgun to n bọ.
Oloye Igboho fi da awọn eeyan Ibarapa loju pe asiko idẹkun to fun gulegule ijinigbe ati ipaniyan latọwọ awọn ti wọn furasi pe wọn jẹ fulani darandaran lagbegbe naa.

Kini Seriki Fulani sọ fun BBC bayii?
Amọṣa Seriki Fulani ni ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Saliu Abdulkadir ti ke gbajare sita.
O ni pe gbogbo ile oun ni wọn jo, bẹẹni ọkọ pupọ lawọn eeyan kan jo pẹlu lasiko ti wọn ya bo gaa oun lagbegbe Iganagan lọjọ Ẹti.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Seriki Fulani Abdulkadir ṣalaye pe ọgọọrọ awọn eeyan ti oun furasi pe wọn jẹ ọmọlẹyin Oloye Sunday Igboho.
Ati pe wọn ya wọ Gaa oun lati dana sun awọn dukia olowo iyebiye nibẹ ti wọn si tun gbẹmi awọn eeyan oun kan pẹlu.
Gẹgẹ bi Seriki Fulani, Alhaji Saliu Abdulkadir ṣe sọ fun BBC News Yoruba ninu ifọrọwerọ kan, gbogbo awọn ile to wa nibẹ ni wọn dana sun pẹlu ọkọ atawọn ohun miran.
Alhaji Abdulkadir ni n ṣe lawọn oṣiṣẹ alaabo n woran lasiko ti igbesẹ ati dana sun gaa naa n waye ni.
Seriki ni ibudo ifarapamọ si ni oun atawọn eeyan oun wa bayii ti wọn ti n sọrọ.
O fi kun un pe gbogbo ileri ti Oloye Igboho ṣe lo mu ṣe ti ko si si agbofinro to daa lọwọ duro.
- Eré ìdárayá 'push-up' ni wọ́n fi ṣe pàṣán na àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí kò tẹ́lẹ̀ ìlànà Covid-19
- Iléẹjọ́ ní kí ìyà akẹ́kọ̀ọ́ Iléẹ̀kọ́ Deeper Life tó ní wọ́n fipá bóun lòpọ̀ yé sọ̀rọ̀ mọ́ lórí ayélujára
- Wo orílẹ̀-èdè tí ọ̀kọ̀ọ́kan àwọn aṣojú Naijiria yóò ti ṣiṣẹ́ jákèjádò àgbáyé
- Ooni Ile ife ṣàlàyé ohun tí Tinubu níló fún ilépa ipò ààrẹ lọ́dún 2023
Kini Sunday Igboho sọ fun BBC bayii?
Nigba ti a kan si ikọ Oloye Sunday Igboho, ohun ti wọn sọ ni pe ko si oun to jọọ rara.
Koda, wọn ni pe Oloye Sunday Igboho ko de gaa Seriki Fulani naa rara ni Igangan lanaa.
Wọn ni: "bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan agbegbe naa rọ ọ lati tẹle awọn debẹ" ṣugbọn ti Igboho rọ wọn lati ṣe suuru ni ibi ti wọn de duro naa nitori alaafia ni ipinlẹ Ọyọ paapaa julọ lagbegbe naa".
Ikọ Igboho sọ pe: Nibẹ lo si ti fi ye wọn pe oun n pada bọ lagbegbe naa ni ọsẹ to n bọ pẹlu ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ lati le e mu oju aje konisọ.
Ni ipari agbẹnusọ Igboho ni pe: "O ṣeeṣe ko jẹ wi pe lẹyin ti Baba kuro nibẹ lawọn eeyan agbegbe naa lọ kuku fi ibinu wọn han ti wọn fi ṣe bẹẹ,
ṣe ẹyin naa mọ pe lọjọsi ti baba lọ, lẹyin ti baba kuro nibẹ awọn fulani kan ṣi kọlu awọn eeyan agbegbe naa ti wọn si pa ninu wọn"
- Gbèǹdéke ku àsìkò díẹ̀, Seriki Fulani fohùn ránṣẹ́ sí Sunday Igboho
- Okuǹrin oníyàwó mẹ́ta fún ọmọ ọdún méjìlá lóyún, ó ní ₦200 ni òun fi tàn án jẹ
- Kí ló ṣokùnfà ikú okùnrin tó dédé dákẹ́ nídìí ọkọ̀ rẹ̀ yìí?
- Buhari buwọ́lu bílíọ̀nù N6.45b láti dá ibùdó afẹ́fẹ́ gáàsì sílẹ̀ fún ìtójú àwọn alárùn covid-19
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani























