Indonesia: Eré ìdárayá 'push-up' ni wọ́n fi ṣe pàṣán na àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí kò tẹ́lẹ̀ ìlànà Covid-19

eeyan Indonesia

Oríṣun àwòrán, others

Bi a ṣe n ṣe nilẹ yii, eewọ ibomii ni.

Lo difa fun bi awọn alasẹ lorilẹ-ede Indonesia ṣe fun awọn ọmọ ilẹ okeere to tapa si ofin Covid-19 lorilẹ-ede naa, ni ijiya to yanilẹnu.

Ninu fidio kan to n kaakiri ori ayelujara laarin ọsẹ yii, ni awọn ọmọ ilẹ okeere to lọ fun irinajo afẹ ni erekusu Bali, ti n se ere idaraya ninu orun, ti wọn si n laagun.

Ni ṣe ni awọn oṣiṣẹ eleto aabo to wọ ibomu duro ti wọn.

Àkọlé fídíò, Joe Biden Innauguration: Tani ìyàwó Joe Biden tí yóò jẹ obìnrin akọ̀kọ nílẹ̀ Amẹrika?

Ọdun to kọja ni awọn alasẹ erekusu Bali sọ ibomu wiwọ di dandan, nitori bi coronavirus ṣe n pọ si nibẹ.

Ọga kan nileesẹ eto aabo orilẹ-ede naa, Gusti Agung Ketut Suryanegara sọ pe "l'ẹ́nu ọjọ mẹta yii, diẹ kọ ni awọn ọmọ ilẹ okeere ti ọwọ ti tẹ nibẹ, lasiko ti wọn ko wọ ibomu.

Àkọlé fídíò, America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀

Eeyan to le ni aadọrin si lo ti san ẹgbẹrun lọna ọgọrun Rupiah ($7) fun owo itanran.

Sugbọn ọgbọ̀n eeyan to sọ pe awọn ko ni owo l'apo ni wọn sọ pe ko ṣe ere idaraya 'push-up'.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Awọn ti ko ni ibomu rara ṣe aadọta, nigba ti awọn to ni sugbọn ti ko wọ ọ daadaa ṣe mẹẹdogun.

Iru ijiya yii naa ni wọn fun awọn kan to jẹ ọmọ orilẹ-ede Indonesia to ṣẹ ẹsẹ yii.

Àkọlé fídíò, US Vice President:Ẹ wo ìtàn obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ igbákejì Ààrẹ ilẹ́ Amẹrika?

Awọn alasẹ erekusu Bali si ti sọ pe awọn yoo le ajeji ti ko ba tẹle ilana Covid-19, kuro lorilẹ-ede awọn

Eré ìdárayá 'push-up ni wọ́n fi ṣe pàṣán na àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí kò tẹ́lẹ̀ ìlànà Covid-19 ní Indonesia

Àkọlé fídíò, LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...