Ooni advise to Tinubu: Ooni Ile Ife pàrokò sí Tinubu pé kó lo ọgbọ́n dípò agbára f' ọ́dún 2023

Ooni

Oríṣun àwòrán, @ooni

Ooni advise to Tinubu: Ooni Ile Ife pàrokò sí Tinubu pé kó lo ọgbọ́n dípò agbára f' ọ́dún 2023

Ọọni Ilẹ Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja keji ti paroko ranṣẹ si Asiwaju Bola Tinubu pe ohun to nilo julọ ni ọgbọn dipo agbara ninu ilepa rẹ lati di Aarẹ lọdun 2023.

ooni Tinubu

Oríṣun àwòrán, others

Lasiko to fi n gbalejo awọn eekan ilẹ Yoruba to n ja fun idije Asiwaju Bola Tinubu fun ipo aarẹ lọdun 2023, SWAGA ni afin rẹ nile Ifẹ.

"Eekan ọmọ Oduduwa ni Asiwaju Tinubu jẹ, inu gbogbo wa lo si n dun sii"

Ọọni Ogunwusi tun pe fun iṣọkan ilẹ Yoruba paapaa laarin awọn oloṣelu to wa lati ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria.

O ni awọn oloṣelu " yii kan naa gbọdọ kọkọ mojuto ọrọ ara wọn nitori awọn yii kan naa lo n ti ẹgbẹ oṣelu kan bẹ si omiran."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Ooni wa rọ awọn to n satilẹyin fun ilepa Tinubu lati di aarẹ naa pe, "Ọgbọn ni ẹyin ati olori yin nilo, kii ṣe agbara."

Ọọni Ile ifẹ ni aisi iṣọkan ko lee ran ẹya Yoruba lọwọ ni igbaradi fun ibo ọdun 2023.

Ooni rọ awọn oloṣelu lati maa mu anfani apapọ Yoruba ṣaaju dipo imọtaraẹni nikan.

O ni l'ọpọ igba wahala ati laasigbo ni iwa awọn oloṣelu maa n jasi fun araalu.

Àkọlé fídíò, Joe Biden Innauguration: Tani ìyàwó Joe Biden tí yóò jẹ obìnrin akọ̀kọ nílẹ̀ Amẹrika?